Primate Ayodele fèsì lórí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ ₦150m tí Adebayo Adelabu fi kàn án

Àwòrán Primate Ayodele wọ aṣọ Àlùfáà àti fìlà aláwọ̀ búlúù àti Adebayo Adelabu wọ aṣọ agbada aláwọ̀ funfun àti fìlà ofi aláwọ̀ Goolu.

Oríṣun àwòrán, Collage

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Primate Ayodele, Oludari ìjọ Inri Evangelical Spiritual Church nilu Eko ti fèsì padà sáwọn ẹ̀sùn kan tí Mínísítà feto ohun Amusagbara, Oloye Adebayo Adelabu fi kan an.

Lọ́jọ́ Ẹtì àná ni ìròyìn jáde síta nínú èyí tí Adelabu tí lọ fi ẹjọ́ Ayodele sun ajọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS pé ó fẹ gbá òun ní owó tó to Mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́jọ naira.

Owo yìí ni Adelabu sọ pé Ayodele ni òun yóò fi ba ṣe àwọn iṣẹ́ ẹ̀mí tí yóò fi wọlé ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo to fẹ́ díje fún nínú ibo 2027.

"Èmí kọ́ ní mo pe e, Adelabu lo ránṣẹ́ si mi pé òun dìje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2019 àti 2023, tí òun sì kùnà"

BBC News Yorùbá wa kan si Ayodele láti gbọ́ èsì lẹ́nu rẹ lórí àwọn ẹ̀sùn tí mínísítà náà fi kan an.

Nígbà to ń ba BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, Ayodele ni òun kọ lo pe Adelabu àmọ́ Mínísítà náà fúnra rẹ lo wa bá òun.

" Èmí kọ ní mo pe, Adelabu lo ránṣẹ́ si mi pé òun dìje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2019,, òun kùnà àti ní ibo 2023, tí òun sì tún kùna.

Àmọ́ eleyi to ń bọ̀ ni 2027 yìí, òun gbọ́dọ̀ wọlé ìbò gómìnà náà ni torí òun nilo rẹ, òun fẹ́ di gómìnà ni tipa.

O ni Asiwaju lo ni kí òun pada lọ sínú ẹgbẹ́ tí òun wà láti díje, ó sọ àwọn nnkan pupọ fún mi àmọ́ àgbàlagbà ni mí, ó sì kéré sì mi, mo gbọ́dọ̀ jo ẹnu."

"N ko béèrè owó lọ́wọ́ rẹ̀, ìgbésẹ̀ ni mo ní ko gbe, tí kò bá sì fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ náà, o pari"

Ayodele tẹsiwaju pé Adelabu lo bi òun pé kí ni òun máa ṣe, tí òun sì sọ fún pé kò lọ sí ọjà láti ra àwọn èròjà náà fúnra ara rẹ.

"O ni pé èlò ni, mo ní mi ò mọ, mo sọ fún pé kí ọmọ rẹ kan àti ọmọ mi kan lọ sí ọjà, òun fúnra rẹ lọ sí owó àwọn èròjà náà sì ₦150 million, kìí ṣe èmi.

N ko béèrè owó lọ́wọ́ rẹ̀, èmi ni mo sọ fún pé ìgbésẹ̀ tó máa gbé ní eleyi, ìgbésẹ̀ ni mo ní ko gbe, tí kò bá sì fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ náà, o pari. "

Primate Ayodele ni kí wọn béèrè lọ́wọ́ Adelabu bóyá òun fún ní nọ́mbà akanti òun ni banki pe ko sanwó síbẹ̀?

O ni òun ni ibẹru Ọlọ́run, tí a sì máa ń ṣe ayẹwo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ wá pupọ.

" Àmọ́ ẹni tí Adelabu ran sì mi jẹ ẹni tí mo fẹ́ràn púpọ̀, òun ló ṣe bá mi sọ̀rọ̀ tí mo ṣe gbọ.

Fèrè Saxophone ni Mọ̀ ni ko lọ rà, tó bá ní mo ní kó ká àwọn nkan kan , ṣe nnkan èṣù ni mo ní kó ká?

"Ṣé mo ní kó pa èèyàn kò fi rúbọ ní àbí ẹ̀mí eeyan ni mo ní kó ká? Ọmọ náà, ẹrú ń bá torí pé ó mọ pe oun ko ni ìwà láti di gómìnà."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣé mo ní kó pa èèyàn kò fi rúbọ ní àbí ẹ̀mí eeyan ni mo ní kó ká?

Ọmọ náà, ẹrú ń bá torí pé ó mọ pe oun ko ni ìwà láti di gómìnà."

Ayodele ni òun ṣetán láti ro ẹjọ́ tòun náà níwájú àjọ DSS torí pé ẹ̀sùn ibanilorukọjẹ lọ mú wá.

O fikùn pé ẹni tí ẹnu rẹ kó bá ti bí, kò lè ṣe asiwaju ìlú, ó sì ti fúnra ara rẹ pé òun kò le se Oludari torí kò jí inú, ẹni tó bá sì ní laakaye ni wọn ń fi sípò ọba.

"O fẹ bá mi lórúkọ jẹ ní, kò bá tiẹ̀ jẹ ki n lu òun ni jìbìtì na, kò tó wà pariwo torí ó ti mọ pe oun ko le jẹ nkankan àmọ́ ó fẹ́ yí ọ̀rọ̀ náà lè mi lórí.

Tension mu ni, ojo lo mú, ó sì máa tọrọ àforíjìn fún nnkan to ṣe.

Oun lo ń bẹbẹ, ó sì ránṣẹ́ sì mi. Tipẹtipẹ la tí sọ pé kò múra àdúrà, àdúrà là ní kó ṣe.

Ẹni tó rán sí mi sì wá láyé àmọ́ ń kọ ní dárúkọ ẹni náà,àgbàlagbà ni mí."

Ayodele ni ko yẹ kí oun da sọ̀rọ̀ Adelabu nígbà tí kii ṣe pé oun fẹ́ pa lo ṣe lọ sọ́dọ̀ DSS,.

O ni ó fẹ́ lo owó ìjọba ni lati fi bá òun ja, agbára àti owó ló ń sì ń gùn, òun sì máa wo ibi tí yóò bá dé.

Ipò Gómìnà Oyo: Adelabu kọ̀wé ẹ̀sùn jìbìtì N150m sí DSS, pé Primate Ayodele fẹ́ gbá òun

Adebayo Adalabu ati Primate Elijah Ayodele

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Adebayo Adalabu ati Primate Elijah Ayodele

Minisita eto Agbara ati ina mọnamọna lorilẹede Naijiria, Bayo Adelabu, ti kọwe ifisun si ajọ DSS, eyi to fi ni gbajugbaja pasitọ, Primate Elijah Ayodele, gbiyanju lati gba owo N150m lọwọ oun.

Ninu iwe ti Adelabu kọ si DSS, lo ti ṣalaye pe Primate Ayodele, oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Oke Afa, nipinlẹ Eko, beere owo naa ko le ba oun ṣe e toun yoo fi di gomina ipinlẹ Oyo.

Iwe naa tẹsiwaju pe ọpọ nnkan eelo iṣẹ ẹmi ti owo rẹ ko mọ niwọn ni Alufaa Ayodele beere lọwọ minisita naa.

Adelabu ṣalaye pe Primate Ayodele beere owo naa lati fi ba oun ṣẹgun iṣoro ati di gomina Oyo nipa lilo ilana ẹmi.

Ẹ o ranti pe Bayo Adelabu ti du ipo gomina ipinlẹ Oyo ri, ṣugbọn ipo naa ko ja mọ ọn lọwọ.

O si tun ti kede bayii pe oun yoo dije pada to ba di 2027.

"Ẹ wadii Primate Ayodele daadaa, kẹ ẹ si jẹ ko yi iran eke to n ri pada''

Ninu iwe ifisun ti minisita eto agbara naa kọ si DSS lo ti ni wọn ni lati wadii Primate Ayodele gidi.

O ni wọn si tun ni lati paṣẹ fun un pe ko yi iran eke to n ri pada, ko si tun tọrọ aforiji pẹlu.

Ninu lẹta naa ti Oludamọran pataki fun Adelabu, Bolaji Tunji, kọ lọjọ kẹtala oṣu Kẹwaa ọdun 2025 si ọga agba DSS, lo ti ni Alufaa Ayodele n sọ awọn iran eke fun Adelabu, ko le ba gba owo nla lọwọ rẹ nitori ipo gomina ti Adelabu fẹ lọ fun.

"Mo kọwe yii lati pe akiyesi ajọ DSS si iwa idọgbọn gbowo lọwọ ẹni, ẹtan ati awọn iwa alumọkọrọyi ti ẹni kan to n pe ara rẹ ni pasitọ, tawọn eeyan mo si Primate Elijah Ayodele, ti ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, n hu.

"Iwa rẹ ti ko idaamu ba Ọlala Adebayo Adelabu, Minisita eto Agbara, ti iwa naa si tun le da omi alaafia ilu ru, to si le ko ba ilana oṣelu ipinlẹ Oyo."

Ninu lẹta naa ni Adelabu ti ni iṣẹ ilu toun fẹ ṣe ko nilo ẹtan lati ọdọ pasitọ, o fi kun un pe ifẹ ilu lo fẹ mu oun dije.

Ki ni awọn nnkan ti Primate Ayodele beere lọwọ Adelabu?

Gẹgẹ bi ẹka iroyin ayelujara kan, The Cable, ṣe ro o, yatọ si owo ti Adelabu ni Primate Ayodele ni koun san, awọn nnkan miran to tun ni ko pese ni:

Asia ẹgbẹ APC mẹrinlelogun, awọn fere oyinbo ti a mọ si saxophones/trumpets, ẹgbẹrun kan.

Owọ awọn fere igbalode naa ko si din ni 30m fun aloku iru rẹ ni Naijiria, ti tuntun lati orilẹede China si jẹ 130m.

Wọn ni ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹrin ni Alufaa Ayodele sọ pe ki Adelabu ko awọn nnkan yii wa, ko too pada sun un siwaju di ọjọ kẹrin.

Mi o gbiyanju lati lu Adelabu ni jibiti, oun funra rẹ lo kọkọ waa ba mi- Primate Ayodele

Primate Elijah Ayodele laaarin awọn to n fọn fere, gbogbo wọn wọ aṣọ funfun to ni ipele alawọ aro lori.

Oríṣun àwòrán, @Primate Elijah Ayodele

Nigba to n ṣalaye ara rẹ lori ẹsun yii, Primate Elijah Ayodele, gẹgẹ bi ẹka iroyin The Cable ṣe ro o, sọ pe:

"Mi o ba a lorukọ jẹ, a ko si ni idunaa-dura kankan. Lẹẹkan si i, owo kankan ko da wa pọ.

"Mo sọ awọn nnkan kan fun un, ko si gba. Mi o gbiyanju lati gba owo lọwọ rẹ. Iye to ba wu mi ni mo le ta ọja mi.

"To ba wu mi, mo le pe e ni biliọnu kan naira, ti ohun ti mo gba a fun ba ti jẹ́.

"Ki lo de to o fi kọkọ waa ba mi to ba jẹ pe o ko gbagbọ ninu mi? Ki ni iwọ naa n ṣe pẹlu ẹni ti o sọ pe iran eke lo n ri?

"Ẹ jẹ ko maa sọ ohun to ba wu u.

"Emi ki i ṣe otoṣi. Mo maa n gbọ bukataa awọn eeyan to ba ku diẹ kaati fun. Oluwa bukun mi."

Bẹẹ ni ẹka iroyin naa ro o.

BBC News Yoruba gbiyanju lati ba Primate Elijah Ayodele sọrọ lori ẹsun yii, ṣugbọn nọmba rẹ ko lọ.