Coronavirus Cases in Africa: Adarí àwọn agbóòkú tó ń fi ijọ́ dárà ní ilẹ̀ Ghana sọ bí àwọn ṣe da ìlúmọ̀ọ́ká

Àkọlé fídíò, Adari awọn agboku ni ile Ghana to n fi ijo dara ba BBC sọrọ lori bi wọn ṣe da ilumọọka.

Ọdun meji sẹyin ni akọroyin BBC ṣe afihan bi awọn agbokun ni orilẹede Ghana ṣe tayọ pẹlu bi wọn ṣe n gbe oku jọ.

Nibayii, wọn ti di ilumọọka lori ayelujara pẹlu bi awọn eniyan ṣe n lo fidio bi wọn ṣe n jọ pẹlu posi lati fi kilọ fun awọn eniyan pe ewu n be loko longẹ fun ẹnikẹni ti ko ba tẹlẹ awọn ilakalẹ to le e dẹkun ajakalẹ arun Coronavirus.

Adari awọn agboku naa, Benjamin Aidoo ni oun ko lerọ rara pe oun le e di ilumọọka, amọ inu oun dun gidigidi.

Aidoo ni ireti wi pe ti arun Coronavirus ba ti kuro nilẹ, awọn yoo bẹrẹ si ni kọ awọn eniyan kaakiri agbaye bi awọn ṣe n ṣiṣẹ wọn.