Àwọn afurasí darandaran ṣoró ní ìpínlẹ̀ Ondo, wọ́n pa ènìyàn mẹ́ta, jó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé àti oko.

Oríṣun àwòrán, Others
Inú fo, àyà fo ní àwọn ènìyàn ìlú Melenge, ìjọba ìbílẹ̀ Ose ní ìpínlẹ̀ Ondo wà báyìí bí awọn afurasi darandaran ṣe yabo ìlú náà níbi tí wọ́n ti pa ènìyàn mẹ́ta, tí wọ́n sì dáná sun àwọn ilé.
Ìròyìn sọ pé àwọn afurasí náà ṣe àkọlù sí àwọn ará ìlú náà, tí wọ́n sì dáná sun oko wọn nítorí wọn kò gbà kí wọ́n da ẹran joko.
Adarí ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn ìpínlẹ̀ Ondo, Olóyè Adeleye Adetunji tó fìdìí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀ ní lọ́gán ni àwọn ènìyàn sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nígbà tí àwọn afurasi náà ṣàkọlù sí wọn.
- Mi ò retí kí àwọn ọmọ Naijria gbóríyìn fún mi lẹ́yìn ìṣèjọba mi - Buhari
- Mi ò ní sin òkú ọmọ mi títí màá fi rí ìdájọ́ òdodo gbà, kò báà jẹ́ ọgbọ̀n ọdún - Baba Sylvester Oromono
- Àwa náà ṣetán láti ma gbé oúnjẹ àti máàlù wà silẹ Igbo- Oloúnjẹ̀ ilẹ̀ Àríwá
- Oṣù díẹ̀ ṣẹ́yìn lé fún mi nítorí bí ojú ìyá mi tó fọ́ ṣe tún le koko - Funmi Awelewa
- Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀ èdè Kenya dá aṣòfin kan dúró nítorí súùtì
Adetunji ní ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti mọ àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi ọ̀hún ṣùhbọ́n tó ní àlàáfíà ti jọba padà ní ìlú náà.
Kọmíṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Oyeyemi Oyediran, tó ṣe àbẹ̀wò síbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún júwe rẹ̀ bí i ìwà ìpànìyàn.
Oyediran jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fojú àwọn tó lọ́wọ́ níbi ìwà láabi yìí winá òfin.
Agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá, Odunlami Funmilayo ní Kọmíṣọ́nà ti da àwọn ọlọ́pàá sí ìlú náà fún ààbò ẹ̀mí àti dúkìá wọn.
Bákan náà ló rọ ẹnikẹ́ni tó bá ní ìmọ̀ nípa àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí láti fi tó àgọ ọlọ́pàá létí.












