Yemi Osinbajo: Ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀sìn kò lè pín Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Tolani Ali
Emir ìlú Katagum ní ìpínlẹ̀ Bauchi Alhaji Umar Farouk ti kan sárá sí Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ṣíṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ onídàgbàsókè ní orilẹ̀ èdè Nàìjíríà pàápàá jùlọ ní agbègbè náà.
Igbakeji Aarẹ Ọjọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo lo kopa nibi igbeyawo ọmọ Minisita feto ẹkọ Mallam Adamu Adamu, Fatima Adamu nilu Azare, ipinlẹ Bauchi.
Osinbajo ṣe abẹwo si aafin Emir Katagum ti Emir naa si kan sara si Aarẹ Buhari nigba to n ka awọn àkànṣe iṣẹ́ amáyérọrùn ti o ti ṣe ni ipinlẹ naa.
Lara awọn to ka ni opopona Kano si Maiduguri to gba Azare kọja ati ile ẹkọ giga imọ iṣegun to wa ni ipinlẹ ọhun.
Bakan naa lo yin Aarẹ fun fifun awọn ọmọ ipinlẹ ọhun meji ni ipo Minisita.
Nigba to n sọrọ, igbakeji Aarẹ irufẹ awọn eniyan to wa nibi ayẹyẹ naa ti foju han pe iṣọkan orile ede Naijiria duro ṣinṣin.

Oríṣun àwòrán, Tolani Ali
O ni ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀sìn tabi ipo ko le pin orilẹ ede yii ati wi pe ko si ohun ti kan to le fa ipinya laaarin wa.
Ọjọgbọn Yemi Osinbajo tun dupẹ lọwọ Emir naa fun riri daju alaafia jọba ni ẹkun Katagum rẹ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ Minisita feto ẹkọ fun nini igbagbọ nini iṣọkan orilẹ ede Naijiria.












