Sanwo-Olu: A kò ní ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí kò bẹ̀rẹ̀ sáà ètò ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ kẹrin oṣù Sẹẹrẹ pa

Ilé iṣẹ́ eto ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Èkó

Oríṣun àwòrán, This Day

Àkọlé àwòrán, Ilé iṣẹ́ eto ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Èkó

Adarí àgbà fún ẹ̀ka tó ń rí sí ìpèsè ẹ̀kọ́ tó pójú owó ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Abiola Seriki-Ayeni ti ní ìjọba kò ní èròńgbà láti ti ilé ẹ̀kọ́ kankan.

Ó ní ṣíṣe èyí yóò ṣe àkóbá fún ìkẹ́kọ̀ọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí Seriki-Ayeni fi léde lónìí ṣàfihàn rẹ̀ wí pé ọgọ́rin ilé ẹ̀kọ́ ni kò tẹ̀lé àṣẹ ìjọba tó ní kí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ sáà yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrin oṣù kìíní ọdún yìí.

Nígbà tó ń gbóríyìn fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó tẹ̀lé ìlànà yìí, ní àwọn yóò kọ̀wé ráńṣẹ́, tí àwọn yóò sì tún lẹ ìwé sí ẹnu ọ̀nà àwọn ilé ẹ̀kọ́ to kọ etí ọ̀gbọin sí àṣẹ ijoba.

Ó ṣàlàyé pé ìdarí pé kí àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti ijoba ati aládáni máa lo sáà ètò ẹ̀kọ́ kan náà kìí ṣe tuntun kò sì yẹ kí àwọn kan máa rú òfin yìí.

Bákan náà ló rọ àwọn adarí ilé ẹ̀kọ́ ti tìjọba àti aládáni láti lájọṣèpọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ le wà ní ilé ẹ̀kọ́ lásìkò tó yẹ.

Àkọlé fídíò, Sanya Adegbaye blind Yoruba teacher: Orí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lánàá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gbé ilé ẹ̀kọ́ tó bá kọ̀ láti tẹ̀le ìlànà sáà ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi lélẹ̀.

Bákan náà ni ìjọba ní àwọn ti ń ṣe àkójọ orúkọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí kò wọlé padà sẹnu ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ kẹrin oṣù Ṣẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìjọba ti pá láṣẹẹ.

Adari ẹka to n ri si ikẹkọọ to poju owo, Abiola Seriki-Ayẹni ninu atẹjade kan ni ìjọba koju oro sí àwọn to n kọti ọgbọin si aṣẹ ìjọba.

Seriki-Ayẹni ni gbogbo awọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹ̀kọ́ ni awọn jọ fẹnuko lori bi saa eto ẹkọ odun 2021/2022 yoo ṣe lọ, fun idi eyi ko yẹ ki ẹnikẹni tapa si.

Ó ṣalaye pe gbogbo àwọn ile ẹkọ ni awọn ti fun iwe ifẹnuko yii.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

O wa rọ gbogbo awọn ile ẹkọ lati ri daju ayika wọn wa ni tonitoni bi wọn ṣe n pada sẹnu iṣẹ.