Obìnrin kan dèrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn wíwẹ ọmọ rẹ̀ lómi gbígbóná nítorí kọ́kọ́rọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Àjọ ẹ̀ṣọ́ ara ẹni làbò ìlú (NSCDC) ti fi obìnrin kan sí àhámọ́ fún ẹ̀sùn dída omi gbígbóná lé ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún mọ́kànlá ní Ìpínlẹ̀ Osun.
Nígbà tó ń fìdìí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún múlẹ̀, ọ̀gá àgbà àjọ NSCDC ní ìlú Osogbo, Emmanuel Ocheja sọ wí pé àwọn ará àdúgbò obìnrin náà ló wá fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún tó àwọn létí.
- Ẹ̀tànjẹ lásán ni ètò ààbò tí Tinubu ní yóò dára tí òun bá di ààrẹ Naijiria - Afenifere
- Ọlọ́pàá dá àwọn èrò tó fẹ́ dáná sun iléẹ̀kọ́ Hanifa dúró, ìjọba Kano gbé iléẹ̀kọ́ náà tì pa
- Njẹ́ o mọ nípa ògẹ̀dẹ̀ tuntun tó lè bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lágbàyé?
- Agbẹjọ́rò tó forúkọ 'Yoruba Nation' darapọ̀ mọ́ ẹjọ́ 'Referendum'ẹgbẹ́ òkè ọya CNG ń jíṣẹ́ ara rẹ̀ ni
- Ọlópàá Benin márùn ùn tó halẹ̀ mọ̀ arìnrìnàjò nínú fónrán fídíò tí wà ní gbaga
- A ó kó Ọlọ́pàá àti Sọ́jà síta lásìkò ìdìbò lòdí sí àwọn oní jàǹdùkú, ẹ ṣáà fọkàn tán mi - Buhari
Kini ileeṣẹ agbofinro n sọ?
Ocheja ni ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an múlẹ̀, à ti pé ọmọ tí ìyá rẹ̀ da omi gbígbóná lé lórí ti wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bèrè lọ́wọ́ obìnrin náà ohun tí ó ṣokùnfà tí ó fi da omi gbóná lé ọmọ rẹ̀ lára.\
O ní oun kò mọ̀ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́, à ti pé òun kò mọ̀ ọ́n mọ̀ da omi gbóná lè ọmọ òun lára.
Nígbà tí ọmọ ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrín òun àti ìyá òun, ó ní ìyá òun ń bá òun wí fún sísọ kọ́kọ́rọ́ kan nù ni.
Àjọ NSCDC tún ṣàfihàn ọkùnrin kan, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì, Amos Danbaba Galadima fún wíwa kùsà lọ́nà àìtọ́ ni agbègbè Ita-Obi ni ìlú Ilesha, àti Abdulrahmon Ibrahim fún ẹ̀sùn pé ó jí ọkọ gbé ní Ìpínlẹ̀ Kano.
- Senato Olujinmi ní Fayoṣe ló ń dá PDP Ekiti rú, Fayose ni ọmọlẹ́yìn òun ni gbogbo àwọn tó ń fapájánú
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Gbajabiamila pé: Kò yẹ kí ẹni tí kò kà ju WAEC bíi Buhari jẹ Ààrẹ Naijiria mọ́
- Ilé ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Abia pàṣẹ fún DSS láti san bílíọnù kan Naira fún Nnamdi Kanu
- Níbo ni ìbọn 178, 549 wọlẹ̀ sí níléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà?
- Yíyọ ìkúnpá orí epo bẹntiróòlù lásìkò yìí yóò fi kún ìṣẹ́ àti òṣì eèyàn Nàìjíríà ni- Abdulsalami
- Àwọn àgbà oyè Ibadan fẹnukò láti gbé ẹjọ́ kúrò nílé ẹjọ́
- Lóòtọ́ ni àrùn Lassa ti wọ ìpìnlẹ́ Oyo, àmọ́ ẹ má mikàn- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo













