Ọwọ́ sìkún àjọ ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Náíjíríà tí ba àwọn ọlọ́pàá márùn ùn tó halẹ̀ mọ̀ arìnrìnàjò

Aworan afurasi

Oríṣun àwòrán, Facebook/ngpolice

Njẹ ẹ ranti fọnran fidio kan to gba ori ayelujara kan nibi ti ọlọpaa kan ti n fi ibọn halẹ mọ obinrin kan loju ọna marosẹ ?

Awọn ọga rẹ ti gbe igbesẹ lori ọrọ naa lẹyin ti ariwo araalu gbode kan.

Ohun taa gbọ ni pe ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awọn ti mu awọn ọlọpaa to halẹ mọ awọn arinrinajo kan loju ọna marosẹ Benin si Eko.

Ninu fọnran fidio ti a ti ri aṣemase wọn,nise ni ọkan ninu awọn ọlọpaa yi fọ obinrin kan leti to si tun yinbọn mọlẹ lẹẹmeeji.

Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita loju opo wọn ni Facebook sọ pe sajẹnti Jude Ogudu ati awọn mẹrin mii wa ni ahamọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ.

Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn ti n se iwadii ọrọ naa nipasẹ ẹka wọn ti wn pe ni X-squad.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Ki la mọ nipa fọnran fidio aṣemaṣe awọn ọlọpaa yi

Ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade wọn sọ pe laarin ọjọ kẹtala si ọjọ Kẹẹdogun ni iṣẹlẹ yi waye lopopona marosẹ Benin si Eko.

Ninu fidio yi to wa kaakiri loju opo ayelujara, a ko le sọ nkan to fa ija ṣugbọn kedere la ri ti ọlọpaa kan,iyẹn Jude Ogudu n fi ibinu sọrọ.

Ko fi mọ ni ọrọ sisọ nikan, niṣe lo fọ obinrin kan leti to si loun yoo yinbọn pa.

O yin ibọn rẹ mọlẹ ninu fidio yi ti awọn ọlọpaa rẹ to ku si n fa a wi pe ko ṣe suuru.

A ko ri oju arabinrin naa tabi ti awọn arrinrinajo to ku ṣugbọn o yẹ ki iwadii awọn ọlọpaa tan imọlẹ si iru ọrọ yi

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Ọlọpaa ko ṣẹṣẹ maa halẹ mọ ara ilu

Lorileede Naijiria iṣesi awọn ọlọpaa si araalu jẹ eleyi to n kan ọpọ lominu.

Lọpọ igba ipa ati agidi ni wọn a maa fi ba araalu lopọ eleyi ti a si maa mu ikọlu wa.

Àkọlé fídíò, EndSars Protest:Ọ̀gá Àgba Ọlọ́pàá ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Eko lẹ́yìn ìfẹ̀họ́núhàn EndSars

Ọrọ yi lo mu ki ọpọ ọdọ ṣe iwọde taa mọ si #ENDSARS ni itako idunkoko mọ awọn araalu lati ọwọ ọlọpaa.

Toun ti bi awọn alaṣẹ ti ṣe n sọ pe awọn n kọ awọn ọlọpaa yi lẹkọ biba araalu sepọ to, awọn ti kii huwa bi ọmọluabi ṣi pọ ninu wọn.

Àkọlé fídíò, Awọn oluwọde ENDSARS ba BBC sọrọ

Loju awọn opopona marose, ko jẹ tuntun ki eeyan ri awọn ọlọpaa ki wọn gbegi dina pe awọn n ṣe ayẹwo iwe ọkọ.

Lọpọ igba owo ni wọn a maa gba lọwọ awọn arinrinajo tabi dirẹba ọkọ ni tipa.

Igba tawọn awakọ tabi ero ba yari mọ wọn lọwọ lo maa n ṣe okunfa iru iṣẹlẹ taa ri ninu fọnran fidio yi.

Àkọlé fídíò, 'Mo sọ fún Dókítà pé èmi ò lè gé ọyàn mi, pé ṣọ́ọ̀ṣì yóò fi àdúrà ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ ọmú mi'