Yoruba Nation agitation: Ilana Omo Oodua kò lọ́wọ́ sí ẹjọ́ ìbò 'Refrendum' kankan, àwọn tó ń ṣe é ń jíṣẹ́ ara wọn ni

Awọn ọd kan n wọde fun Yoruba Nation

Oríṣun àwòrán, other

Iroyin kan jade ni Ọjọbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti dara pọ mọ ẹjọ ti ẹgbẹ Coalition of Northern Groups , CNG fun ijọba lati fun ẹgbẹ Biafra to n ja fun idasilẹ orilẹede Igbo lanfani lati ṣeto ibo bẹẹni tabi bẹẹkọ lori idasilẹ orilẹede Igbo.

Amọṣa ẹgbẹ Ilana Ọmọ oodua to jẹ olori agbarijọpọ gbogbo ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ ilẹ Yoruba ṣalaye pe awọn ko mọ nipa rẹ o.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ṣalaye pe iroyin kayeefi lọrọ naa jẹ fun awọn nitori pe awọn ko figbakankan darapọ mọ ẹnikẹni lati pe ẹjọ tabi ṣe ẹjọ nipa ibo bẹẹni tabi bẹẹni kankan.

Kini èrò Ilana Omo Oodua lori agbẹjọrọ naa?

Ọgbẹni Maxwell ṣalaye pe ohun kan ṣoṣo to n ja lọkan gbogbo ọmọ Naijiria ni lati da eto idibo to n bọ lna ni ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun duro lọna to tọna labẹ ofin.

O ni awọn igbesẹ naa yoo bẹrẹ si nii fi ara han fun araye ri laarin ọsẹ diẹ si asiko yii.

Àkọlé fídíò, Kaun

Ni Ọjọbọ ni amofin kan ti orukọ rẹ n jẹ Timilehin Odunwo farahan nibi igbẹjọ ẹjọ kan ti ẹgbẹ Coalition of Northern Groups , CNG pe ijọba apapọ pe ko ṣeto idibo bẹẹni tabi bẹẹkọ fun awọn ajijagbara Biafra lati m boya awọn eeyan eya wọn fẹ lati lọ nitootọ.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Amofin Odunwo to pe ara rẹ ni agbẹnusọ fun awọn to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, iyẹn Yoruba Nation ṣalaye pe idi ti oun fi n darapọ m igbẹjọ naa ni pe kii ṣe ilẹ Igbo nikan lo n ja fun ominra, ilẹ Yoruba pẹlu nifẹsii pẹlu.