False banana: Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa ògẹ̀dẹ̀ tó lè bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rùn èèyàn lágbàyé?

Oríṣun àwòrán, RBG Kew
- Author, Helen Briggs
- Role, Science correspondent
Pẹlu ipenija ti awọn eeyan n koju nipa ipese ounjẹ lagbaye latari iyipada oju ọjọ, orisi ọna lawọn onimọ n wa lati dẹkun ipenija yi.
Ninu awọn ọna abayọ ni wiwa awọn ounjẹ ti ko ni ṣoro lati gbin ti yoo si le bọ ọpọ eeyan.
Ọkan lara awọn ounjẹ yi ni o foju han nipa eso kan to foju jọ ọgẹdẹ.
- Ṣé ẹ ti rí 'Penis Fish,' ẹ̀ja tuntun tó rí bí nǹkan ọmọkùnrin tó lúwẹ̀ẹ́ jáde nínú òkun rí?
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a kò gbọdọ̀ pa àti ọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn
- Ọlọ́pàá Adamawa ni #30,000 ni wọ́n fi bọ́ igún látìmọ́lé
- Ìyàwó Ẹlẹ́ṣìn ìlú Wukari yarí pé láyé òun ò lè gbà kí ọkọ́ òun wọ igbó mọ́ fún ìsìnkú Ọba
- Ọlópàá Benin márùn ùn tó halẹ̀ mọ̀ arìnrìnàjò nínú fónrán fídíò tí wà ní gbaga
Eso yi torukọ rẹ n jẹ enset to si gbajumọ ni Ethiopia lawọn onimọ sọ pe o ṣeeṣe ki o gbọ bukata ounjẹ ọkẹ aimọye eeyan lagbaye.
Ni Ethiopia wọn a maa fi ṣe burẹdi tabi asaro.
Iwadii si tun fi han pe wọn le gbin eso yi lawọn ilẹ miran ni Afrika.
Dokita Wedawek Abebe ti fasiti Hawassa to wa ni Awasa, lorileede Ethiopia sọ pe ''eso yi le ko ipa ribiribi lati koju ipenija ipese ounjẹ ati idagbasoke''
Enset to foju jọ ọgẹdẹ la gbọ pe apa kan Ethiopia nikan ni wọn ti n jẹ.
Eso rẹ to dabi ọgẹdẹ ṣe jẹ ti wọn a si tun maa fi ara eso yi tabi gbongbo rẹ naa se asaro tabi ki wọn fi ṣe burẹdi.

Oríṣun àwòrán, RBG Kew
Enset jẹ ounjẹ gbajumọ fawọn eeeyan to fẹ ẹ to ogun miliọnu.
Nipa iwadii ati ayẹwo,awọn onimọ nipa nkan ọgbin sọ pe Enset ṣe gbin nigbakugba ti awọn eeyan yoo si maa jẹ lasiko ọda.
Dokita James Borrell, ti Royal Botanic Gardens, Kew, sọ pe:
"Eso yi ni awọn anfaani kan to mu ko jẹ eso to le se daada.Ko si igba ti ẹ ko le gbin tabi ki ẹ ka.Nitori naa ni wọn fi npe ni igi to n koju ebi''
Coffee ati awọn nkan ọgbin mii fẹsẹ rinlẹ ni Ethiopia

Oríṣun àwòrán, RBG Kew
Iyipada oju ọjọ jẹ nkan to n ṣe akoba fun nkan ọgbin ati pipin awọn ounjẹ kaakiri Afrika ati awọn ibomiran.
Idi ree tawọn onimọ fi n foju si awọn ounjẹ mi lati koju ebi.
Wọn ni ''bi a ba foju wo, pupọ eronja taa n ri lara ounjẹ a maa wa latara irẹsi, agbado tabi wiiti''
Dokita Borell wa ṣalaye pe ''o yẹ ki a samulo awọn ounjẹ miran nitori ọna kan lo dabi pe a ti n ri awọn eleyi taa n jẹ
Ẹkunrẹrẹ alaye nipa iwadii yi ti wọn gbe jade wa ninu apilẹkọ Environmental Research Letters.

















