Àjọ NAPTIP kílọ́ fún Òbí àti Alágbátọ̀ láti dẹ́kun fífi ọmọ ṣọfà

Oríṣun àwòrán, @NAPTIP
Àjọ NAPTIP kílọ́ fún Òbí àti Alágbátọ̀ láti dẹ́kun fífi ọmọ ṣọfà
Ajọ to n gbogun ti tita eeyan soko ẹru ni Naijiria ti orukọ wọn n jẹ National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP) lo ṣe ikilọ naa.
Àjọ tó ń gbógun ti fífi ọmọ ṣọfà ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NAPTIP) ti ẹkùn Ìpínlẹ̀ Benue sọrọ yii lasiko ti o dá àwọn ọmọ méjìlélọ́gbọ̀n tí awọ́n oniṣẹ ibi fẹ́ fi ṣọfà padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn.
- Wọ́n ṣàwárí òkú ọmọ ọdún mẹ́ta ní Jigawa
- Akọ̀ròyìn pa òwe lórí afẹ́fẹ́, kí ló dé tí Adájọ fi sọ pé ó sọ̀rọ̀ àbùkù sí Aàrẹ?
- Jonathan the tortoise: Wo ìjàpá tó pé ọdún 190, òun ni ẹranko tó dàgbà jùlọ láyé
- Tí Obasanjọ bá fi PDP sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ PDP kò lè kúrò lára rẹ- Iyorchia Ayu. Alágá PDP
- Ẹ̀tànjẹ lásán ni ètò ààbò tí Tinubu ní yóò dára tí òun bá di ààrẹ Naijiria - Afenifere
- Obìnrin kan dèrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn wíwẹ ọmọ rẹ̀ lómi gbígbóná nítorí kọ́kọ́rọ́
- Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...’ rèé
Bawo ni irinajo awọn eeyan naa ṣe bẹrẹ?
Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kìíní ọdún yìí ní àjọ ọlọ́pàá rí àwọn ọmọ náà gbà nígbà tí wọ́n ń kó wọn lọ sí Ìpínlẹ̀ Osun láti lọ fi ṣọfà.
Leyin tí wọ́n sì ti kó wọn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Obí wọn padà pẹ̀lú àtìlẹyìn àjọ NAPTIP ni ìjọba ìbílẹ̀ Ukum ni ipinle Benue.
Adarí NAPTIP ní ìlú Makurdi, Gloria Bai sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ọmọ náà jẹ́ ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́wàá lọ.
Bai ṣàlàyé pé mọ́kànlélógún nínú àwọn ọmọ náà ló jẹ́ pé wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní àwọn ìlú tí ko wọ́n wà.
Bai ni pe koda, awọ́n kàn wálé fún ìsinmi ọdún Kérésìmesì ni.
O ni pe àwọn mọ́kànlá to ku jẹ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lọ fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kaakiri.
Bákan náà ni adari NAPTIP fi kun un pé àwọn tí nawọ́ gán obinrin afurasí, Angbiandoo Akaasema tó fẹ́ lọ fi àwọn ọmọ náà ṣọfà, tó sì ti wà ní àhámọ́.
Ó ní afurasí náà ní ọkọ òun ní àjọ ẹlẹ́yinjú àánú tó fẹ́ ṣe ìrànwọ́ láti rán àwọn ọmọ náà lọ sí ilé ẹ̀kọ́.
Nibo ni iwadii de duro?
Bai tẹ̀síwájú pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá àjọ náà wà tàbí irọ́ ni.
Ni ipari, Bai wá rọ àwọn ènìyàn pàápàá àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn olórí ìlú láti máa ràn àjọ náà lọ́wọ́ nídìí iṣẹ́ wọn.
O ni nípa fífi tó wọn létí nígbà tí wọ́n bá kẹ́fín pé àwọn kan ń fi ọmọ ṣọfà ni agbègbè wọn.
Bẹ́ẹ̀ ló rọ àwọn òbí láti bí iye ọmọ tí wọ́n bá lè tọ, kí wọ́n yé pín àwọn ọmọ wọn fún àwọn ènìyàn tí wọn kò mọ̀ rí.



















