Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni láti pa òwe bú ààrẹ̀ báyìí? Wo òwe tí akọ̀ròyìn kan pa tí wọ́n fí sọ ọ́ sí gbaga

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileẹjọ kan lorileede Turkey ti ni ki wọn fi gbajugbaja akọroyin Sedef Kabas si ahamọ lori ẹsun pe o bu aarẹ ilẹ naa.
Lọjọ Abamẹta ni wọn mu ni Istanbul ti adajọ si paṣẹ pe ki wọn fi si ahamọ ṣaaju igbẹjọ rẹ.
Wọn fẹsunkan pe o fi owe tabuku aarẹ lori eto kan lori afẹfẹ nileeṣẹ amounmaworan ti o niṣe pẹlu ẹgbẹ alatako.
Arabinrin yi sọ pe oun ko jẹbi ẹsunti wọn fi kan an.
Ẹwọn ọdun kan si mẹrin lo le ṣe ti ileẹjọ ba da lẹbi ẹsun yi.
- Tí Obasanjọ bá fi PDP sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ PDP kò lè kúrò lára rẹ- Iyorchia Ayu. Alágá PDP
- Ẹ̀tànjẹ lásán ni ètò ààbò tí Tinubu ní yóò dára tí òun bá di ààrẹ Naijiria - Afenifere
- Agbẹjọ́rò tó forúkọ 'Yoruba Nation' darapọ̀ mọ́ ẹjọ́ 'Referendum'ẹgbẹ́ òkè ọya CNG ń jíṣẹ́ ara rẹ̀ ni- Ilana Omo Oodua
- Ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń wo ìhòhò obìnrin dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta
Ki ni owe to pa yi gaan an
Gbogbo wa naa la mọ pe owe lẹṣin ọrọ, ọrọ si ni ẹṣin owe.Ọpọ igba lawọn sọrọsọrọ a maa fi owe kin ọrọ lẹyin.
Bo ṣe ri ni liki bẹẹ naa lo ri i gbanja lorileede Turkey.
Owe ti wọn sọ pe o pa ati ọrọ to fi gbe lẹyin ni pe''Nilẹ wa Turkey, owe kan wa to sọ pe ori ade a maa gbọn si ni.Ṣugbọn a ri pe ọrọ yi ko ri bẹ''
''Bi maalu ba wọ inu aafin eyi ko ni ko di ọba.Kaka bẹẹ, aafin a maa di ile ta ti n sin ẹran ni''
O pada tun fi ọrọ yi soju opo rẹ ni Twitter.
- Sanusi wọ gau torí pé o kọrin bù Gómìnà Ganduje
- Ọ̀rọ̀ ètò ìlera Nàìjíríà ń bẹ nínú ewu, Buhari ń fọwọ́ ra àwọn agbésùnmọ̀mí lórí - Bakare, Kukah
- Ibí gbogbo làá tií dáná alẹ́ torí náà ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, ẹ 'calm down'- Femi Adesina
- Channels TV sọ̀rọ̀ sókè lórí ìròyìn pé DSS ti gbé òṣìṣẹ́ wọn lórí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Ortom
- Àwọn ojíṣẹ́ Ọlọ́run tó yí Buhari ká kò bá a sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀- Afenifere
Agbẹnusọ aarẹ Erdogan, Fahrettin Altun ṣapejuwe ọrọ rẹ gẹgẹ bi eleyi ti ko bojumu.
Loju opo rẹ ni Twitter o sọ pe ''Niṣe ni akọroyin kan n bu aarẹ wa loju opo tẹlifisan ti wọn ko ni iṣẹ mii ju ki wọn maa se itankalẹ ọrọ inunibini''
Ninu ọrọ rẹ to kọ ni ile ẹjọ, arabinrin Kabas sọ pe kii se erongba oun lati tabuku aarẹ.

Ki lawọn akọroyin ilẹ naa sọ nipa iṣẹlẹ yi
Olootu ileeṣẹ iroyin Tele1 channelMerdan Yanardag ti bẹnu atẹ lu bi wọn ṣe mu arabinrin Kabas
''Bi wọn ṣe sọ si ahamọ ni ago meji ooru nitori owe ko ba oju mu rara.Ọna ati fi gaga di akọrọyin ati awujọ lẹnu leleyi jẹ''
Ọdun mọkanla ni Ogbẹni Erdogan lo nipo olootu ijọba ko to di aarẹ lọdun 2014
Iṣọwọ bo ṣe n pa awọn alatako lẹnu mọ n kọ awọn eeyan lagbaye lominu eleyi to mi ki ọrọ ma gunrege laarin Turkey ati ajọ EU.
- Ilé ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Abia pàṣẹ fún DSS láti san bílíọnù kan Naira fún Nnamdi Kanu
- Akẹ́kọ̀ọ́, ìyá rẹ àtàwọn jàndùkú dá bàntẹ́ ìyà fún olùkọ̀ọ́ l'Ogun
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
- Iléẹjọ́ ní Abuja tó fi ẹ̀sùn tuntun kan olórí ẹgbẹ́ IPOB, Nnamdi Kanu ti sún ìgbẹ́jọ́ sí oṣù tó ń bọ̀
- Oluwo: Ààrẹ Buhari, ẹ dájọ́ ikú fún gbogbo ẹni tó ń gbé òògùn olóró, agbésùnmọ́mi àti afinisoogun owo
- Hajiya Binta Balarabe Kubaus rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he lẹ́yìn tó lu jìbìtì ₦5.5m
- Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá ba akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìyàwó, ikú dé!
Ọkẹ aimọye eeyan ni wọn ti fẹsun kan pe wọn bu aarẹ lati igba to ti de ori alefaa.
Lọdun 2020 iwadii to le ni ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn to ni ṣe pẹlu ẹsun yi ni wọn dawọ le gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe jabọ.















