Nǹkan yan, ilé ẹjọ́ ní kí ọmọ ‘yahoo’ lọ fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ fún osù mẹ́jọ

Oríṣun àwòrán, Other
Ile ẹjọ ti ni ki akẹẹkọ asekagba lẹka imọ nipa eto irinna oko nileẹkọ giga fasiti Tai SolarinAmusa Abdulkareem Oluwasegunfunmi o lọ fọ ile igbọnsẹ ilu fun oṣu mẹjọ gẹgẹ bi ijiya ẹṣẹ rẹ.
Ajo to n gbogun ti iwa ibẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC lo fi ẹsun kan Oluwasẹgunfunmi fun gbigbe idanimọ ẹlomiran wọn lati lu jibiti ti wọn si gbe oun atawọn akẹgbẹ rẹ ninu owo kotọ yii lọ siwaaju ile ẹjọ giga apapọ kan to fi ikalẹ si ilu Osogbo ni ipinlẹ Ọsun.
Ni ogunjọ oṣu kẹfa ọdun 2022 ni ile ẹjọ gbe idajọ kalẹ fun Oluwasẹgunfunmi atawọn akẹgbẹ rẹ ti orukọ wọn n jẹ Ajisafe Sodiq Olaide, Lawal Samuel Morenikeji, Osuolale Abdullahi Abiodun, ati Olamilekan Ridwan Taofeek.
Ẹsun ọtọtọ to da lori jibiti ori ayelujara ni won da ọkọọkan wọn lebi le lori lẹyin ti wọn jẹwọ pe awọn jẹbi ẹsun naa niwaju adajọ to gbọ ẹjọ naa.
Eyi lo mu ki Onidajọ Ayo-Emmanuel ti ile ẹjọ giga apapọ to wa nilu Osogbo o dajọ fun Oluwasẹgunfunmi pe fun osu mẹjọ ni ko fi ṣiṣẹ sin ilu fun ẹsun naa to tako abala ikejilelogun ofin to koro oju si iwa lilujibiti lori ayelujara, ti ọdun 2015.
Pẹlu idajọ yii, yoo maa fọ ile igbọnsẹ ileewe girama Ataoja School of Science, Osogbo, ni ipinlẹ Ọsun.
Bakan naa ni ile ẹjọ naa ni ki wọn si iwe fun lọdọ ọga agba ileewe naa lati mọ bi o ṣe n wa deede si, ki wọn si gbe iwe naa wa siwaju ile ẹjọ lẹyin to ba pari saa ijiya rẹ.
Ẹwe Onidajọ Iyabo Yerima ti ile ẹjọ giga tipinlẹ Ọyọ nilu Ibadan ti ran arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ajisafẹ Sodiq Ọlaide lọ ṣiṣẹ sin ilu fun fifi ọna eru gba owo lọwọ eeyan kan, eleyito tako abala irinwo o le mọkandinlogun, 419 iwe ofin iwa ọdara tipinlẹ Ọyọ tọdun 2000.

Oríṣun àwòrán, efcc
Bakan naa ni Onidajọ Omolara Adeyemi ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ kan naa tun ran arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Lawal Samuel Morenikeji lọ si iṣẹ asekara sinlu fun osu mẹfa, Osuolale Abdullahi Abiodun ati Olamilekan Ridwan Taofeek pẹlu si iṣẹ aṣekara ọlọsẹ kan fun titasẹ agẹrẹ si abala ọrinleri wo o le mẹrin iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọyọ.

Oríṣun àwòrán, other
Ilé ẹjọ́ dájọ́ kí ọmọ Yahoo lọ gbá ilẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
Ile ẹjọ giga kan ni ilu Abuja ti dajọ ki arakunrin oni jibiti ori ayelujara kan ti wọn maa n pe ni Yahoo Boy lorilẹede Naijiria lọ ṣe isinru ilu fun oṣu mẹfa.
Arakunrin ọmọ Yahoo naa ti orukọ rẹn jẹ Chibuike Marshal Omemgboji amọ ti iroyin ni orukọ sajẹ rẹ n jẹ “Surajo Ascensio” ni ile ẹjọ ilu Abuja ni ko lọ maa gba ilẹ ṣọọṣi lojoojumọ fun oṣu mẹfa gẹgẹ bi iṣẹ lilọwọ si itọju awujọ.
Wọn ni o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni Ọjọru ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹfa ni ile ẹjọ ti Adajọ Agba K.N Ogbonnaya ti dajọ pe Chibuike jẹbi ẹsun jibiti ori ayelujara.

Ki ni ẹṣẹ ọmọ Yahoo yii gan?

Ninu atẹjade kan, a gbọ pe Chibuike ṣi oju opo Facebook ati Instagram ayederu eyi to si fi n gba awọn eeyan ni iye owo $4,328 eyi to fẹrẹẹ to miliọnu 2.6 ni iye owo orilẹede Naijiria.
Idajọ naa lọ bayii pe:
“Wipe iwọ Chibuike Marshall Omemgboji ni ọdun 2021 lo ọna ẹburu fi lọ awọn eeyan lọwọ gba nigba too ṣi oju opo ayelujara Facebook ati Instagram too si pe ara rẹ ni Surajo Ascensio leyi ti arabinrin kan, Sarah Vakunta to tun n jẹ Danne Gibbs fi owo to to $4,328 ranṣẹ si apo rẹ labẹ didibọn pe o jẹ ololufẹ rẹ.
Pẹlu eyi, o ti ru abala ofin 320(a) ninu iwe ofin Naijria, Abuja (ọdun 1990) ti ijiya rẹ si wa labẹ abala ofin 322 ninu iwe ofin kan naa.
















