Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ òṣìṣẹ́ bánkì méjì àti èèyàn mẹ́rin mìí tó n gbèrò láti dingunjalè ní Ibadan

Aworan awọn afurasi adijunjale

Oríṣun àwòrán, screenshot

L'ọjọ Aje ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ tẹ awọn oṣiṣẹ banki meji ati awọn eeyan kan to n gbero lati digunjale nile ifowopamọ kan niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun.

Awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ naa ni Abass Azeez ati Mayowa Kehinde. Awọn afurasi ti o ku ni Rildwan Eniola, Mistura Akinade, Abass Aderoju ati Akeem Adeniyi.

Kele ofin gbe wọn nibi ti wọn fi ori pamọ si ni agbegbe 'Akala Expressway' niluu Ibadan.

Lasiko to wọn n fi oju awọn afurasi naa lede, alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifeso ṣe alaye pe l'ọjọ Aje ni kele ofin gbe wọn lẹyin ti wọn ti ṣe eto lati digunjale ni ọkan lara awọn ile ifowopamọ to n bẹ niluu Ibadan ni owurọ ọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa se sọ, awọn afurasi naa ti jẹwọ erongba wọn lati ra nnkan ijagun ati bi wọn ṣe fẹ fi imu finlẹ saaju idigunjale naa.

Osifeso tẹsiwaju pe ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ Ọlọpaa lo se awari erongba awon afurasi naa ti wọn si nawọ gan wọn saaju idigunjale ti wọn n gbero.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe alaye pe isẹ iwadii n tẹsiwaju lati se awari awon alabaṣiṣẹ awọn ọdaran naa, ti wọn si n parọwa si awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lati ta ileeṣẹ olopaa ni olobo, ti wọn ba kẹẹfin ohunkohun ti o le se iranlọwọ fun ileeṣẹ naa ninu iwadii wọn.