Ìgbẹ́jọ́ ikú olórin ẹ̀mí Osinachi Nwachukwu tẹ̀síwájú lónìí, wo ohun tó ti ṣẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Igbẹjọ tẹsiwaju loni, ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, lori iku gbajugbaja akọrin ẹmi, Osinachi Nwachukwu, nile ẹjọ giga nilu Abuja.
ẹnikan lara awọn ẹlẹri to jẹri niwaju ile ẹjọ nibi igbẹjọ naa ni Arabinrin Caroline Madu, to jẹ iya oloogbe.
Nigba to n sọrọ niwaju Onidajọ Njideka Nwosu-Iheme, iya Osinachi fi ẹsun kan ọkọ oloogbe, Peter Nwachukwu, pe o dunkooko lati pa Osinachi, ti oun iya rẹ ba ṣe abẹwo si nile oun.
Gẹgẹ bi mama naa ṣe sọ, oṣu Kejila, ọdun to kọja ni oun ri ọmọ oun kẹhin, nibi isin ṣọọṣi kan, ko to di pe o ku lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2022.
Bakan naa ni iya naa sọ pe lati igba ti Peter ti fẹ ọmọ oun, ni ko ti jẹ ko wa ẹbi rẹ kankan mọ, tabi ki wọn o wa.
O ni ọmọ oun ko wa oun wa si ilu Enugu ri, bẹẹ ni kọ rẹ kii gba a laaye lati gbe ipe oun lori foonu.
“Mo ranti akoko kan ti ara mi ko ya, ti awọn eeyan bẹ Peter pe ko jẹ ki n wa gba itju nilu Abuja. Mo lọ sile ijọsin pẹlu wọn ni ọjọ kan, niṣe ni Peter gbe ọkọ kuro lẹyin isin, to si ko awọn ọmọ nikan lai gbe emi ati iyawo rẹ.”
Mama Osinachi jẹri pe ẹbi oun ti fi igba kan gbe Osinachi kuro nile Peter, nitori bo ṣe ma n lu u. Amọ oloogbe pinnu lati pada si ile rẹ lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹta, nitori pe o ko awọn pasitọ kan wa lati bẹbẹ.

Oríṣun àwòrán, other
Arabinrin Madu ṣalaye pe nkan ti ọmọ oun sọ fun oun ni pe aisan ọgbẹ inu lo n ṣe oun, amọ ọkọ rẹ sọ ṣaaju pe jẹjẹrẹ ọna ọfun lo pa a.
O ni awọn eeyan to kọkọ gbọ iku ọmọ oun lori ẹrọ redio lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, lo wa si ile oun lati kẹdun. Ẹnu wọn lo ti gbọ pe ọmọ rẹ ti ku.
“Nigba to di bi aago meje alẹ, Peter fi nọmba foonu Osinachi pe mi pe ọmọ mi ti ku.”
O ni oun ran Peter leti ileri to ṣe wi pe ti Osinachi ko ba kuro nile oun ni aaye, yoo kuro ni oku.
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Oríṣun àwòrán, other
Arabinrin Osinachi ti awo orin "Ekwueme" tan irawọ rẹ kariaye jade laye lọjọ kọjọ oṣu kẹrin ọdun 2022 lẹyin ti wọn ni o ni ọgbẹ inu lookan aya rẹ nitori iya ati lilu lọwọ ọkọ rẹ.
Ẹni ọdun mejilelogoji ni.
Oniruuru ẹsun lawọn mọlẹbi arabinrin yii pẹlu awọn ọmọ ati awọn to sun mọ ọ fi kan kọ rẹ pe lilu bi baara nii maa n lu akọrin ẹmi naa lati igba ti wọn ti fẹra wọn.
Eyi ti fa ọpọ awuyewuye lorilẹede Naijiria lori iwa ifiyajẹ ọkọ tabi aya ẹni.
Awọn ọlọpaa fi panpẹ ofin mu Peter Nwachukwu, ọkọ akọrin ẹmi naa ti wọn si bẹrẹ iwadii lọgan lara eyi ti ṣiṣe ayẹwo iku rẹ ni ilana iṣegun oyinbo ti jẹyọ.
Ẹsun onigun mẹtalelogun ti wọn fi kan Peter nipe oun lo ṣokunfa iku iyawo rẹ Osinachi lẹyin ọpọlọpọ lilu bi bara.














