Àwọn àjíǹigbe ró pé owó wà lọ́wọ́ ìjọ ẹlẹ́sìn Kristi ni ìkọlù ṣé ń wáyé- CAN Oyo

Oríṣun àwòrán, CAN
Alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ẹka ti ipinlẹ Oyo, Apostle Joshua Akinyemi ti ọpọ lara awọn ajinigbe ni o rope awọn ile jọsin ni owo lọwọ latari bi ijọ methodist ṣe gba itusile bisọọbu kan pẹlu owo to to ọgorun milonu naira.
Olori ijọ Methodist Prelate Samuel Uche Kanu ni awọn ajinigbe tu silẹ laipẹ lẹyin ti awọn ajinigbe gba owo idoola miliọnu ọgọrun Naira.
Apostle Akinyemi ni o ṣeeṣe ki eleyi wa lara idi ti ikọlu ṣe n waye ni awọn ile jọsin ni orilede ede Naijiria nitori ọpọ ninu awón ajinigbe naa rope owo wa ninu ijọ oni gbagbọ
“Nigba ti wọn ba le ko owo to to ọgorun milonu naira laarin wakati merinlelogun, eyi lo fun ọpọlọpọ wọn ni igboya pe ti awọn ba ji onigbagbo kan gba, owo ma jede nibi.”
“Ko kin ṣe eleyi nikan, wọn ti gbe awọn ni oke ọya tipẹtipẹ sugbọn ọlọrun ma ko wa yọ ninu ikọlu naa.”
Akinyemi tẹsiwaju pe awọn ile jọsin ni lati dẹkun ijọ sin alẹ, ki wọn si gba odẹ pẹlu wọn lati ma sọ lọwọ awọn ajinigbe naa.
O ni igbinyanju awọn ajinigbe naa ni lati di awọn ọmọ onigbagbo lọwọ lati sin ọlọrun sugbọn ko ni waye nipa ti adura.
“A ni le ni anfani lati ma ṣe isin ni oru, ti ọpọ si tun gbe isin wa si ojumọmọ nitori ikọlu ati ibẹru awon ajinigbe sungbọn awọn ile jọsin ni lati gba ọdẹ lati ma sọ wọn lọwọ ikọlu na.”
Akinyemi wa ro awọn Olusọ ati awọn ọmọ lẹyin kristi lati dẹkun iririn ajo ni asa alẹ nitori ikọlu awọn ajinigbe naa.
Láàrin oṣù mẹ́tàdínlógún, wo iyé Pásítọ̀, Olùsọ àti ìjọ tó kò sì ọwọ àwọn àjíǹigbe àti agbébọn ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọpọlọpọ ile jọsin ni o ti di titi pa latari bi ikọlu ṣe waye ni origun mẹrin orilede Naijiria ti ọpọ olusọ, bisọọbu, alufa ati awọn ọmọ lẹyin kristi ti bo si ahamọ awọn ajinigbe.
Awọn miran ti gba ibẹ lọ si ọrun ti awọn kan ni lati san ọpọlọpọ milonu fun awọn ajinigbe lati gba itusile lọwọ awọn ajinigba naa.
Ninu wọn, awọn kan ti gba ibẹ lọ si ọrun ti awọn kan ni lati san ọpọlọpọ milonu fun awọn ajinigbe lati gba itusile lọwọ awọn ajinigba naa.
Njẹ ki ni a le pe ni okunfa ikọlu si awọn ile ijọsin?
Ajọ International Society for Civil Liberties & the Rule of Law ni ọdun 2021 sọ pe ọdun naa jẹ ọdun ibanujẹ fun ọpọ ọmọ kristi lẹyin ti Oluso meẹdọgbọn se agbako iku ojiji ati ijinigbe lọwọ awọn ajinigbe, ti ikolu si n waye si ile jọsin to to irinwo ni ye. Oṣu Marun un akoko ninu ọdun 2022, Ajọ ọmọ lẹyin kristi ti ṣe akosilẹ oluso meewa ti o ti sa'gbako ijinigbẹ.
Ikọlu Owo
Aipẹ yi ni Daosisi Ijọ Aguda ti ilẹ Naijiria sin oku gbogbo awọn to gbẹmi mi ni ikọlu si ẹka ṣọọṣi naa ni ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo.
Awọn agbesunmọmi lo ṣekọlu si ile ijọsin St. Francis Catholic Church ni ilu Ọwọ, ti wọn si ṣina bolẹ pẹlu ado oloro lu awọn ọmọ ijọ ni asiko ẹsin ni Ayajọ Pentecost.
Biṣọọbu Daosisi Ijọ Aguda ti ipinlẹ Ondo, Ẹniọwọ Jude Arogundade kede pe eniyan mejidinlogoji lo ku ninu iṣẹlẹ ikọlu to waye ni ilẹ jọsin naa.
Bi Olori ijọ Methodist ṣe san N100 Miliọnu
Bakan naa, olori ijọ Methodist Prelate Samuel Uche Kanubo ko si ọwọ awọn ajinigbe ti o si gba itusilẹ lẹyin ti ajọ ọmọlẹyin Kristi Naijiria san ọgọrun un milonu Naira.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ BBC, Kanu sọ pe lẹba ọna ni ipinlẹ Abia nigba toun n lọ si papakọ ofurufu ni awọn ajinigbe yi yọ si oun loju ọna.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oluso ijọ Celestial ti wọn ji gbe
Ni ijọ Celestial Church of Christ to wa ni Ewekoro, Olusọ meji lo bo si ahamọ awọn ajinigbe
Olusoagutan ile ijosin Celstial naa, Oluwatomisin Ehuwaojomo to fi idi isẹlẹ naa mulẹ ni ijọ naa san milionu kan naira, ọpọlọpọ siga, ọti lile Orijin ati Irẹsi, fun awọn ajinigbe naa ki wọn to gba itusile awọn oluso meji naa.
Laipẹ ni Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna fìdi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn tun ṣe ikọlu si awọn ile ijọsin meji ati awọn ni ipinlẹ naa. Yatọ si awọn tí awọn agbebọn naa ṣekupa, ọpọlọpọ ni wọn ji gbe lọ.

Oríṣun àwòrán, screenshot












