Bí wọ́n ṣe fi ipá bá ọmọ mi lòpọ̀ dé ojú ikú rèé ní Imo – Bàbá Ọmọ

Imo Rape: Baba Amarachi Favour ṣàlàyé bí wọ́n ṣe fi ipá bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀ títí dé ojú ikú

Aworan Emeka ati awon omo re

Baba Amarachi Favour Ohakelem to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogun ti ṣalaye bi wọn ṣe fi ipa ba ọmọ rẹ lopọ de oju iku ni ilu Imo.

Ninu ọrọ rẹ, o ni Amarachi ọmọ oun jẹ ẹni ti kii sọrọ rara, ti kii si ba awọn eniyan ṣe.

‘’Iṣẹ oogun tita lo n kọ ki wọn to pa ọmọbinrin naa nipaṣẹ ifipabanilopọ’’

Agbegbe ijọba ibilẹ Ehime Mbano ni ipinlẹ Imo lo ti waye ti afurasi si ti salọ.

Baba Amarachi, Emeka Jude Iwunze ni ọdọ baba oun ni ọmọ naa n gbe, to si nko nipa tita oogun ni ipinlẹ Imo.

O ni ẹgbọn oun lo lọ ba baba oun pe ki ọmọ naa wa ba wọn ṣe ounjẹ fun aburo ọkọ rẹ lasiko ayẹyẹ ti wọn n pe ni ‘’ wearing of cloth’’.

Ayẹyẹ naa ni wọn n ṣe ni ọjọ Satide naa lati kede pe ọmọ naa ti balaga, to si ti di ọkunrin.

Emeka to n gbe ni ilu Eko ni awọn ẹgbọn ọhun ati ọkọ rẹ n gbe pẹlu afurasi naa ninu agboole kan naa.

Amarachi kọkọ di awati

O ni ohun to ṣẹlẹ ni pe mọlẹbi wọn Theresa lo kọkọ n pe Favour ti nọmba rẹ ko si lọ, to si ni ki oun lọ ṣabẹwo si wọn.

‘’Theresa ripe nkan ko lọ deedee pẹlu bi o ṣe n pe, ti kosi ẹni to gbe aago rẹ.

Theresa de ibẹ ko si ri Amarachi to si bere lọwọ Chinyere pe nibo ni ọmọbinrin naa wa.

Oun ti wọn sọ nipe awọn ti wa gbogbo agbegbe naa wọn ko ri.

Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si ni wa ti wọn si ri ninu yara afurasi nibi to dubulẹ si.

Wọn gbe digba digba lọ si ileewosan amọ o ti ku ki o to de ibẹ.

Emeka ni inu to bi awọn ọdọ agbegbe naa lo mu ki wọn dana sun ile naa, amọ ti afunrasi naa si ti fẹsẹ fẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, BBC Pidgin

Emeka ni oun ti oun fẹ ni idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa, ki iku ọmọ oun ma ṣe jasi asan.

Nibayii, Chinyere ati ọkọ rẹ naa ti fẹsẹ fẹ, amọ Theresa ati Uche wa ni agọ ọlọpaa.

Kini awọn ọlọpaa mọ nipa iṣẹlẹ naa?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Imo, Micheal Abattam fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ to si ni awọn meji ti wa ni panpẹ ọlọpaa

Amọ wọn ṣi n wa afurasi naa nitori o ti salọ

Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni lootọ ni awọn ọdọ dana sun ile ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.