Ob̀inrin yìí pa ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó ko ìwé nípa ‘How to murder your husband’

'How to murder your husband': Ob̀inrin yìí pa ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó ko ìwé nípa ‘bí o ṣe lè pa ọkọ rẹ’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Arabinrin Onkowe nipa ifẹ Nancy Crampton Brophy ti jẹbi ẹsun ipaniyan lẹyin to yinbọn pa ọkọ rẹ.

Nancy naa ni iwadii fihan pe o ti kọkọ kọ iwe jade nipa bi oun yoo ṣe pa ọkọ naa ninu iwe to pe akọle rẹ ni "How to murder your husband".

Oṣu to kọja ni ileẹjọ da ẹjọ pe Crampton Brophy to jẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọrin jẹbi ẹsun ipaniyan.

Wọn ni ọdun 2018 ni lo pa ọkọ rẹ ti wọn ti jẹ lọkọ laya fun ọdun mẹrindinlọgbọn.

O pa ọkọ rẹ nitori ọrọ owo ti won ma a san fun igbayegbadun, life insurance $1.5m (£1.2m), ti ọkọ rẹ ba ku.

Ki o to pa ọkọ rẹ naa ni Brophy ti jẹ ilumọọka onkowe to si ti kọ iwe awọn ololufẹ bi "The Wrong Husband" ati "The Wrong Lover".

Ohun to mu ki awọn eniyan maa sọrọ nipa rẹ ni ohun to ti kọ tẹlẹri nipa bi eniyan ṣe le pa ololufẹ rẹ.

‘’Ko si ẹni ti ko le pa ẹlomiran ti wọn ba gbe ẹmi rẹ gbona’’

Bakan naa lo tun sọ pe ko si ẹni ti ko ni lara lati pa eniyan, ti wọn ba gbe ẹmi rẹ gbona, lẹyin naa lo lọ fagile.

O tun ṣalaye ọna ti eniyan le gba lati pa ọkọ rẹ, to fi mọ lilo ibọn, ọbẹ ati oogun oloro ati awọn apaniyan bẹẹ bẹẹ lọ.

Onkọwe naa ni to ba jẹpe pipa ọkọ oun yoo tun oun silẹ ninu igbekun, nitori naa oun ko ni duro ninu igbekun naa.

 Adajọ kan ni awọn ko le fi iwe to kọ naa ṣe idajọ rẹ nitori o tipe ki o to ṣẹṣẹ pa ọkọ rẹ naa.

Amọ wọn fi idi rẹ mulẹ pe o mọọmọ pa ọkọ rẹ ni, to si ni lọkan lati ṣekupa ọkọ rẹ naa nitori ati danikan na owo gọbọi ti wọn yoo san lẹyin iku ọkọ rẹ.

Obinrin naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun nitori oun ko ranti nkankan to ṣẹlẹ ni aarọ ọjọ ti ọkọ rẹ ku naa.

Ẹwọn gbere ni wọn da fun arabinrin naa, amọ awọn agbẹjọro rẹ ni awọn yoo lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun.