Kò sí àyè láti pàrọ̀ olùdíje igbákejì àarẹ lábẹ́ òfin – INEC sọ fún Tinubu àti Obi

Aworan tinubu ati Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, INEC ti sọ àrídájú rẹ̀ pé kò sí ààyè fún fífi ẹnìkan dógò bíi igbákejì sípò Ààrẹ tí wọ́n yóò pàrọ̀ lọ́jọ́ iwájú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú kan ti n gbèrò láti ṣe.

Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹfà ni gbèdéke tí àjọ INEC fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú dà láti fi orúkọ àwọn olùdíje sípò Ààrẹ àti àwọn igbákejì wọn ráńṣẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú parí ètò ìdìbò abẹ́nú.

cyí ló ṣokùnfà tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú fi ń wá ẹni tí yóò ṣe igbákejì àwọn tí wọ́n yàn sipò bí olùdíje ipò Ààrẹ kí wọ́n le bá gbèdéke tí àjọ INEC fún wọn.

Ìdí nìyí tí Bola Tinubu ti ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC àti Peter Obi ti Labour Party fi fi orúkọ àwọn igbákejì tí wọ́n ní ó ṣeéṣe kí àwọn yọ kúrò tó bá yá síta ná.

Ẹ̀wẹ̀, adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àti ìròyìn ní àjọ INEC, Festus Okoye ní fífí ènìyàn kan dógò gẹ́gẹ́ bí igbákejì lòdì sí ìwé òfin ètò ìdìbò Nàìjíríà.

aworan oludije ẹgbẹ oselu Labour Party

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Okoye ní irú ìwà yìí jẹ́ ohun tuntun tí àwọn olóṣèlú ń gbé wọ ètò ìdìbò.

Ó ṣàlàyé pé òfin tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ẹnìkan kò lè dá díje, wọ́n gbọ́dọ̀ mú ẹnìkan tí wọ́n yóò jọ gbé àsíá ẹgbẹ́ dání ni.

“Ní ti wa, àwọn olùdíje ti fi orúkọ àwọn tí wọ́n jọ fẹ́ dupò ráńṣẹ́ sí wà, kò sí ibì kankan tí wọ́n tọwọ́bọ̀ láti sọ wí pé fìdíẹ ni orúkọ àwọn ènìyàn tí àwọn fi kalẹ̀.”

Bákan náà ló fi kun pé tó bá pọn dandan fún wọn láti ṣe àyípadà igbákejì kankan, igbákejì tí orúkọ rẹ̀ wà ní ọ̀dọ̀ àwọn ló ní ẹ̀tọ́ láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí INEC pé òun ti yọwọ́ nínú ìdíje náà pẹ̀lú àṣẹ láti ilé ẹjọ́.