Wo bí Adebolu Adejobi tó ní ìpèníjà ara "Cerebral Palsy" ṣe ṣeé tó di akẹ́kọ̀ọ́ tó páàsì "WAEC" ju gbogbo ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ
Adebolu Adejobi jẹ ọmọ ti Eleduwa mọọmọ da lai wo ti ipenija ara to ni tori gbogbo ẹni to ba ti ni ipenija ara lawọn eeyan maa n gbagbọ pe wọn o wulo fun ohunkohun mọ. Niṣe lo jawe olubori gẹgẹ bi akẹkọọ to fakọyọ ju ninu idanwo WAEC laarin gbogbo awọn ti wọn jọ n kawe ni ile ẹkọ giga Ajayi Crowther Memorial School fun saa ẹkọ ọdun 2021. Adejobi ni arun ti oloyinbo n pe ni "Cerebral Palsy" eyi to maa n jẹ ki ara rẹ gbọn ni gbogbo igba, ko lee da rin, ko lee da wa nibi kan ko si tun lee sọrọ dada ki eeyan gbọ.
Bawo ni arun Cerebral Palsy ṣe maa n ṣe Adebolu?

Bẹẹ ba wo o daadaa, gata gata ni irin ẹsẹ rẹ ti gbogbo ara yoo maa gbọn, bo ba fi ọwọ mu nkan, o lee jabọ, ete ati eyin ẹnu rẹ ko figba kan duro dede tori a maa lọ sibi sọhun ni to ba n sọrọ.
"Nigba ti mo ba n rin, awọn rẹ mi maa n sọ pe, wo bi eleyii ṣe n rin, waa ṣubu, lọ sun, maa duro sile, ma gbe nkankan".

"Amọ ni temi, mo jẹ ọmọ ti mo maa n da duro ninu ile". O ni bo tilẹ jẹ pe oun jẹ ọmọ to kan n lọ ileewe lati maaki orukọ, oun o le kawe afi igba ti baba kan ni adugbo awọn ni oun yoo maa kọ ọ niwe lede Yoruba. Ninu ifọrọwanilẹnu wo ti BBC Yoruba ni pẹlu rẹ, o ṣalaye bo ṣe tayọ laarin ẹlẹgbẹ ati pe imọlara oun funrararẹ gẹgẹ bi ẹni ti o di gbajumọ nitori ohun ti ọpọlọpọ ro pe ko le ṣeeṣe fun ẹni to ba ni ipenija ara bii tirẹ. O sọ fun BBC pe "Mo pinu nínú ọkàn mi pé mo fẹ́ kí àwọn òbí mi mọ pé wọn kò ṣe àṣedànù".













