Lẹ́yìn ọdún 91, adájọ́ ní ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Ọmọkunrin alawọ dudu lorilẹede Amerika to jẹ ọdọmọde nigba naa ni wọn pa ni ọdun 1931 lẹyin ti ileẹjọ ni o jẹbi ẹsun ipaniyan.

Amọ lẹyin ọdun mọkanlelaadọrun, ileẹjọ Pennsylvania ti ni ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ẹgbọn rẹ obinrin to ku fun un lo ja titi lati ripe idajọ otitọ waye lori iṣẹlẹ naa.

Arakunrin ti wọn pa naa, Alexander McClay Williams, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogun ni awọn agbẹjọro ati adajọ to jẹ alawọ funfun da ẹjọ iku fun ni agbegbe ila oorun orilẹede Amẹrika.

Amọ lẹyin ọdun mọkanlelaadọrun ni adajọ miran da ẹjọ ti wọn fi kan an nu, ti wọn si ni Williams ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ẹgbon rẹ obinrin ọhun ni inu oun dun pe idajọ ododo pada jade bi o ṣe yẹ ko ri lati ibẹẹrẹ.

Kilo ṣẹlẹ ni ọdun 1931?

Aworan arakunrin naa

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Asiko naa jẹ igba ti awọn alawọdudu ma n jẹya lai ni idi, ti ẹlẹyamẹya si peleke si.

Ni Oṣu Kẹwaa, ọdun 1830 ni ọkọ Vida Robare ti wọn ti kọ ara wọn silẹ ba oku iyawo rẹ to jẹ nọọsi ni ile ibojuto awọn ọmọ alaigboran, Glen Mills School for Boys.

Lẹyin naa ni wọn fi ẹsun kan Williams pe oun lo ṣekupa obinrin naa.

Lai si igbẹjọ to ye kooro, laarin wakati mẹrin ni awọn adajọ to jẹ alawọ funfun da ẹjọ iku fun arakunrin naa.

Amọ awọn eniyan ti wọn ko gbagbọ pe idajọ otitọ ni idajọ iku naa ja fitafita fun otitọ, ki idaj̣o ṣẹṣẹ to yipada ni ẹyin aadọrun ọdun.