How Abiodun Oyebanji won in Ekiti: Fídíò bí Oyebanji ṣe la Oni, Kolawole mọ́lẹ̀ rèé

Àkọlé fídíò, Báyìí ni wọ́n ṣe kéde olùdíje APC Abiodun Oyebanji lóru mójúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ajáwé-olúborí

Kedere ni oju awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan la kalẹ ni ibudo ajọ eleto idibo INEC to wa ni ipinlẹ Ekiti nibi ti wọn ti ka gbogbo esi idibo ijọba ibilẹ kọọkan.

Oru mọjumọ oni si ni wọn pari rẹ gẹgẹ baa ṣe n mu awọn esi idibo naa jade fun yin lọlọkan o jọkan.

Ẹwẹ, ni kete ti wọn ka awọn esi idibo naa tan ni Ọjọgbọn Fasiti ti ajọ INEC gba lati wa ṣe alamojuto agba nibi idibo naa, Ọjọgbọn Kayode Adebowale kede ẹni to jawe olubori.

O ṣalaye bi ohun gbogbo ṣe lọ ni ibamu ofin ajọ INEC

Fídíò bí Oyebanji ṣe la Segun Oni ti SDP ati Bisi Kolawole ti PDP mọ́lẹ̀ rèé.