Ǹkan márùn ún tí Atiku ní òun yóò ṣe nìyìí tó bá di Ààrẹ

Aworan Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Google

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti ni ohun to kan bayii ni ipolongo kaakiri orilẹede Naijiria.

Abubakar sọ eyi lasiko to n kede gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa gẹgẹ bi ẹni ti yoo dije dupo igbakeji aarẹ Naijiria ni idibo ọdun to n bọ.

Atiku ni awọn nkan marun un to ṣe pataki si oun, ti oun fẹ tẹramọ ti oun ba di aarẹ orilẹede Naijiria ni;

Dida iṣọkan Naijiria pada

Atiku Abubakar ni orilẹede Naijiria lọwọ bayii fihan pe ko si irẹpọ ati iṣọkan laarin awọn ẹya to wa ni orilẹede Naijiria.

 Amọ igbesẹ akọkọ ti oun yoo gbe ni lati ripe iṣokan pada laarin awọn eniyan fun ilọsiwaju orilẹede.

Dida Alaafia Pada

Atiku ni ọkan gboogi ninu idojukọ ti Naijiria n koju lọwọ ni aisi aabo to peye.

O ni oun yoo fopin si Ikọ agbesunmọmi Boko Haram, ISWAP, awọn ajinigbe ati gbogbo awọn ọdaran ni Naijiria.

Dida eto ọrọ aje to gbooro pada

Titi di asiko yii awọn onimọ ni ọrọ aje Naijiria ko kẹsẹjari nitori ọrọ owo epo to n ja walẹ lagbaye.

O ni oun yoo ṣe atunṣe ti igbayegbadun awọn ọmọ Naijiria yoo gbooro si.

Ẹka Eto ẹkọ yoo gba atunṣe

Atiku ni lati ileẹkọ alakọbẹrẹ to fi de fasiti ni eto ẹkọ Naijiria ti nilo atunṣe ti oun yoo si ripe atunṣe naa waye.

O ni awọn olukọ to kọṣẹ mọ iṣẹ ni awọn yoo gba si ibi iṣẹ, ti oun yoo si ṣe atunṣe kikọ awọn ileẹkọ to wuyi fun wọn.

Agbeyẹwo iwe ofin Naijiria

Orisirisi agbeyẹwo lo ti waye nipa iwe ofin Naijiria, ti ọpọlọpọ ọmọ Naijiria to fi mọ awọn aṣofin gbagbọ pe iwe ofin naa nilo agbeyẹwo.

Atiku Abubakar ni oun yoo ṣe eyi lati mu ifimọṣọkan lori iwe ofin naa ati idagbasoke ba orilẹede Naijiria.

Nibayii, gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo ti dibo abẹle lati yan aṣoju wọn ninu eto idibo sipo aarẹ to n bọ lọdun to n bọ,amọ awọn onimọ ni ifigagbaga naa yoo wa laarin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lori ẹni ti yoo di ipo aarẹ mu ni Naijiria.