O ti fihàn pé lóòtọ́ ni o kò sí fún ẹnikẹ́ni, Tinubu kọ̀wé ráńṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti kan sáárá sí Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ipa ribiribi tó kó níbi ètò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà.
Tinubu ní ṣaájú kí ètò ìdìbò abẹ́nú náà tó wáyé ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ni àwọn ti ń bẹ Ààrẹ Buhari láti kéde ẹnìkan gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jẹ Ààrẹ lẹ́yìn ṣùgbọ́n Ààrẹ kọ̀ jálẹ̀.
Nínú ìwé àkọráńṣẹ́ kan tí Tinubu kọ sí Ààrẹ Buhari èyí tí olùbádàmọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ lórí ìròyìn àti ìpolongo, Femi Adesina fi léde ni Tinubu ní ó hàn gbangba pé Ààrẹ Buhari kò sí fún ẹnìkan ní tòótọ́.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ni àwọn ti ń retí kí Ààrẹ kéde pé ẹnìkan tí òun fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí olùdíje, ṣùgbọ́n Ààrẹ kọ̀ láti yan ẹnìkan sójú tó sì fún gbogbo àwọn láyè láti díje.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìwúrí fún òun tí inú òun sì dùn pé Ààrẹ dúró dáńfó gedegbe láàárín gbogbo àwọn olùdíje pàápàá nígbà tí oníkálùkù bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Tinubu fi kun pé lásìkò ìbò gan ní òun ṣàwárí rẹ̀ pé gbogbo àwọn olùdíje ni Ààrẹ Buhari ń fẹ́, ní èyí tó ní ó hàn nínú akọráńṣẹ́ tí Ààrẹ Buhari kọ́kọ́ kọ sí òun láti fi kí òun kú oríire ìjáwé olúborí.
Ó tẹ̀síwájú pé inú òun dún pé gbogbo àwọn ènìyàn ẹgbẹ́ àwọn yan òun gẹ́gẹ́ bí olùdíje wọn, àmọ́ ó ní èyí kò ní ṣeéṣe tí Ààrẹ Buhari kò bá fọwọ́ si.
Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ipa takuntakun tí wọ́n kó lásìkò ètò abẹ́nú náà.
Ó ní gbogbo àwọn ìpèníjá tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra ni òun yóò ri dájú pé òun fi sínú ètò ìpolongo àti pé ohun ni àwọn yóò kojú.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní òun ti ń kàn sí àwọn tí àwọn jọ díje ní ọ̀kọ̀ọ̀kan lójúnà láti mú ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú bá ẹgbẹ́.















