"À máa tẹ́le àṣẹ ilé ẹjò láti fí ọjọ́ kún ìfórúkọsílẹ̀, gbígba káàdì àwọn olùdibo"- INEC

aworan fifi orukosile

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, Independent National Electoral Commission (INEC), ti ni awọn yoo tẹle asẹ ile ẹjó lati ṣe afikun si ọjọ kun iforukọsilẹ fun kaadi idibo alalopẹ (PVC).

Komisana fun ajọ INEC, Festus Okoye lo sọ eleyi di mimọ nigba ti o kopa lori telifisan Channels lonii.

O ni ajọ naa ni o wa labẹ ofin orilẹede Naijiria ti o si gbọdọ tẹle asẹ to wa lati ile ẹjọ.

“Ajọ INEC jẹ ajọ ti o wa labẹ ofin ti a si gbọdọ ṣe nkan ti ile ẹjọ ni ki a ṣe.”

Kaadi idibo PVC

Oríṣun àwòrán, inec nigeria/facebook

Idajọ naa lo waye latari bi ajọ Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) ṣe gbe Ajọ eleto idibo ni Naijiria lọ si ile ẹjọ lori afikun ọjọ fun iforukọsile kaadi idibo lati fun ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni anfani lati ṣe iforukọsilẹ naa.

Adajọ Mobolaji Olajuwon ti ile ẹjo giga olu ilu Naijiria, Abuja lo gbe igbẹjo naa kalẹ, ti o si paa lasẹ fun Ajọ eleto idibo ni Naijiria, Independent National Electoral Commission (INEC) lati ṣe afikun naa.

Mọ̀ síi nípa ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí ó rọrùn láti fi rí káàdì ìdìbò rẹ gbà

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, Independent National Electoral Commission (INEC), ti da Ọgbọnjọ oṣu Kẹfa, ọdun 2021, gẹgẹ bi gbedeke fun iforukọsilẹ fun kaadi idibo alalopẹ (PVC).

Eyi jẹ ara imurasilẹ ajọ naa fun idibo gbogboogbo ti yoo waye ni oṣu Keji, ọdun 2023.

Kaadi yii nikan ni irinṣẹ ti araalu ni lati yan oludije to ba wu wọn si ipo oṣelu lasiko eto idibo.

Bawo lo ṣe le gba kaadi PVC rẹ?

Ki o to o le gba kaadi idibo alalopẹ, o gbọdọ mu iwe pelebe ti ajọ INEC fun ọ, nigba to o ṣe iforukọsilẹ fun kaadi.

Amọ to ba jẹ pe o ko tii ni iwe pelebe naa dani, o le lọ si oju opo ayelujara ajọ INEC, lati fi orukọ silẹ tabi ki o lọ si ileeṣẹ ajọ naa to ba sunmọ agbegbe rẹ.

Ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni iforukọsilẹ lori ayelujara yoo wa sopin.

Igbesẹ fun iforukọsilẹ lori ayelujara

Lọ si oju opo ajọ INEC, lati fi akọsilẹ nipa rẹ sibẹ.

Lẹyin naa ni wa a tẹ iwe pelebe to ni gbogbo nkan ti o kọ jade

Eto yii wa fun awọn to ba fẹ paarọ tabi ṣe ayipada ibi ti wọn ti kọkọ gba kaadi idibo wọ

Bakan naa lo tun wa fun awọn to ba a fẹ ṣe atunṣe lori orukọ wọn

Awọn to ba fẹẹ ṣẹṣẹ forukọ silẹ naa le lo o

O tun le beere fun kaadi miran ti eyi to n lo tẹlẹ ba ti bajẹ tabi sọnu lori ayelujara

Inec gbe eto ori ayelujara yii silẹ lati mu adinku ba iye eero ti oo ma awa ni awọn ọfiisi rẹ.

Awọn oludibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbesẹ to kan ni lati lọ si ọfiisi ajọ Inec:

Lẹyin ti o ba ti kọ gbogbo nkan to yẹ nipa rẹ silẹ lori ayelujara, igbesẹ to kan ni pe ki o lọ si ọfiisi ajọ Inec to ba sun mọ tabi awọn ibudo ti wọn pese

Nibẹ ni wọn o ti gba akọsilẹ nipa ika ọwọ rẹ ati aworan rẹ ‘biometric capture’

Kaadi idibo alalopẹ rẹ yoo si di tiẹ nigba ti ajọ Inec ba ṣe e jade

Awọn wo lo le gba kaadi idibo alalopẹ, PVC?

Eto yii wa fun awọn ọmọ Naijiria to ti pe ẹni ọdun mejidinlogun, ti ko si forukọ silẹ ri.

Awọn to ti gba kaadi ri, amọ ti wọn ti kuro ni ilu tabi agbegbe ti wọn ti gba kaadi akọkọ

Awọn oludibo ti kaadi idibo wọn ti kán, sọnu tabi bajẹ.

Ati awọn oludibo to fẹ ṣe atunṣe orukọ lori kaadi wọn atijọ.

Ajọ eleto idibo Inec sọ pe miliọnu meje din ẹgbẹrun lọna igba, 6.8 millino, eeyan lo fi orukọ silẹ fun igba akọkọ lati oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ti eto naa bẹrẹ pada.

O ni miliọnu marun-un din diẹ ninu wọn lo jẹ akẹẹkọ, oniṣowo ati awọn iyawo ile.

Lọ si oju opo ayelujara yii lati wo ibudo ajọ Inec to sun mọ ọ:

Oju opo ayelujara yii lo wa fun iforukọsilẹ ati atunṣe si kaadi idibo: