Oyè ibadan kìí ṣe fún títà, Ganduje lẹ́tọ́ọ̀ sí i - Olubadan sọ̀rọ̀ lórí oyè Fiwajoye

aworan gomina kano pelu oludije fun ipo Aare APC

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Olubadan ti ilẹ ibadan, Ọba Lekan Balogun Alli Okunmade II, ti ni ifinijẹ oye ni ilu ibadan ni ki n ṣe fun tita lẹyin ti o kede Gomina Ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ati iyawo rẹ ọjọgbọn Hasatu Ganduje gẹgẹ bi Aarẹ Fiwajoye ati Yeye Aarẹ Fiwajoye.

Ayẹyẹ naa lo waye ní gbọgan Mapo ní ilu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ, ẹkun gusu iwọ oorun orílẹ-ede Nàìjíríà.

Olubadan ni oye naa yoo mu irepo ati iṣọkan wa laarin guusu iwọ-oorun ati ariwa iwọ oorun oorun orílẹ-ede Nàìjíríà.

O tẹsiwaju pe Gomina Ganduje jẹ apẹẹrẹ oni iwa tutu latari bi o ṣe gbe igbesẹ alafin nigba ti rogbodiyan waye laarin yoruba ati hausa lọja Sasa niluu Ibadan’.

Kabiyesi ni fun idi eyi lo jẹ ki ilu ibadan fi oye Fiwajoye fun gomina, ti ko di lọwọ oṣelu ninu tabi rira oye naa.

“Oye yii ni yoo mu iṣọkan ati ibagbepo wa laarin ilu Ibadan ati Ilu Kano paapa julọ ni yoo pẹ fun iṣọkan alafia ni orilẹ ede Naijiria pẹlu.”

“Oye Ibadan ki n ṣe fun tita, ẹni ti o ba tọsi ni a ama fun, Gomina Abdulahi Umar Ganduje si lẹtọ si oye Fiwajoye naa.”

aworan gomina ipinle kano ati iyawo re

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje pe fun emí isọkan àti ìbagbepọ laarin ọmọ orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti Ọba Lekan Balogun, Alli Okunmade II fi oun ati aya rẹ ọjọgbọn Hafsatu Ganduje jẹ oye Aarẹ Fiwajoye ati Yeye Fiwajoye Ile ibadan.

Ganduje wa fi asiko naa dupẹ lọwọ Olubadan Ilẹ Ibadan ati gbogbo awọn igbimo Olubadan fun Oye tí wọn fi oun ati aya rẹ Hafsatu jẹ, to sì gba a ladura kí ibaṣepọ to ti wa laarin ilẹ Ibadan ati ipínlẹ Kano tubọ tẹ síwaju.

Aworan gomina ipinlẹ Kano ati iyawo rẹ

Lara awọn to peju síbẹ ni Asiwaju Ahmed Tinubu; Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ẹni tí Komisana ijọba IbIlẹ ati Ifinijoye, Oloye Bayo Lawal soju rẹ ẹ; Emir ilu Kano, Aminu Ado Bayero; Emir Bichi, Nasir Ado Bayero; Asiwaju Olubadan Ilẹ ibadan, Amofin Teslim Folarin; Alaga ẹgbẹ oṣel APC, Isaac Omodewu, ati awọn eeyàn jake jado orílẹ-ede Nàìjíríà.