“Phone repairer” tó pín àwòrán ìhòhò obìnrin oníbarà rẹ̀ lórí ayélujára rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá he
Ọkùrin tó pín àwòrán ìhòhò obìnrin lórí ayélujára gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ kan ni Ghana ti ran ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, to n tun foonu ṣe ni ẹwọn ọdun mẹrinla lẹyin to jẹbi ẹsun pe o pin aworan ihoho obinrin kan lori ayelujara.
Solomon Doga sọ nile ẹjọ naa pe oun gba pe lootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn ki adajọ fi iye denu.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa bẹ ile ẹjọ ọhun fun idariji, adajọ ni ko lọ ṣẹwọn ọdun mẹrinla fun gbigba owo lori aworan ihoho obinrin naa, ati ọdun meji mii fun pinpin aworan naa lori ayelujara.
Bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Ghana News Agency, GNA, ṣe jabọ, ọga ọlọpaa kan, Maxwell Lanyo, sọ fun ile ẹjọ naa pe ilu Accra ni obinrin ọmọ orilẹ-ede Lebanon naa ti n ṣiṣẹ.
Obinrin naa ran awakọ lati ṣe foonu ọhun lọdọ awọn to n tu foonu ṣe, nibẹ ni afurasi yii ti yẹ inu kọrọ-kọndu foonu naa wo to si ri awọn aworan ihoho obinrin naa nibẹ.
Lẹyin naa ni afurasri ọhun fi awọn aworan naa ranṣẹ si obirin naa, to si n bere owo lọwọ rẹ.
Iṣẹlẹ naa bi obinrin ọhun ninu, o si kọ lati fi owo ranṣe si Doga, amọ ṣe ni Doga lọ fi awọn aworan naa lede lori ayelujara.
Ko pẹ lẹyin igbesẹ naa ti awọn ọrẹ atawọn alabaṣiṣẹ obinrin naa bẹrẹ si n pe lori ago pe awọn ri aworan ihoho rẹ lori ayeliujara.
Amọ kaka ko kawọ gbera, ni ṣe lo fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, ti wọn si ṣawari afurasi ọhun lati fi ṣikun ofin gbe.
O lodi si ofin lati maa pin aworan ihoho awọn eeyan tabi gba owo lori rẹ lorilẹ-ede Ghana.












