Ìjọba Oyo pín ₦500m fún àwọn olókoòwò kékèké

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Ijọba ipinlẹ Oyo ti pin ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira fun awọn olokowo kekeke ti iye wọn le ni ẹgbẹrun meji lati ṣowo.
Owo ọhun, to jẹ owoya ni wọn pin labẹ eto Sustainable Action for Economic Recovery (SAfER).
Ṣaaju ni gomina Seyi Makinde ti kọkọ ṣeleri pe ijọba oun yoo pese owo naa fun awọn olokowo ọhun, eyii ti wọn yoo san pada pẹlu ele diẹ.
Owo naa ni ijọba Oyo pin nipasẹ awọn ile ifowopamọ alabọde meje kaakiri ipinlẹ ọhun.
Awọn ile ifowopamọ naa ni Ebedi Microfinance Bank, Iseyin; Fullrange Microfinance Bank, Ibadan; Kadupe Microfinance Bank, Saki; Isale Oyo Microfinance Bank, Oyo; Caretaker Microfinance Bank, Ogbomoso; Excel Microfinance Bank, Ibadan; ati NUT Oke Bola Microfinance Bank, Oke Bola, Ibadan.
Apapọ iye awọn oṣiṣowo to ri owo naa gba, gẹgẹ bii atẹjade ijọba ni 2,078.
Nigba to n sọrọ lori owo naa, alaga SafER, Otunba Segun Ogunwuyi ni gomina Makinde gbe igbesẹ ọhun lọna sti ṣatilẹyin fun awọn oniṣowo kekeke, ati pe ijọba mọ ojuṣe wọn lara eto ọrọ aje ipinlẹ naa.
Ogunwuyi, to tun jẹ olori oṣiṣẹ gomina Makinde ni ọpọ oniṣowo ipinlẹ Oyo lo jẹ oniṣowo kekeke.
O fi kun pe niwọn igba ti ijọba ba le ṣatilẹyin fun wọn, yoo rọrun fun awọn eeyan naa lati ṣowo ati lati jere, eyii ti yoo mu ọrọ aje ipinlẹ ọhun gboro siwaju si.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko si makaruru kankan ninu bi awọn ṣe mu awọn to ri owo naa gba.
O sọ pe awọn ile ifowopamọ ti wọn ba dowopọ lo kede awọn ti owo ọhun tọ si, ati iye to tọ si ẹnikọọkan wọn.
Lẹyin naa lo rọ awọn to ri owo ọhun gba ki wọn na lori ohun ti wọn gba owo naa fun.














