Wo bí oge títa pẹ̀lú elòmíràn ṣe lè ṣe ìrànwọ́ fún ìbáṣepọ̀ ìwọ àti olólùfẹ́ rẹ

Aworan ololufe meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Biba awọn eeyan ta oge dabi ẹbun fawọn eeyan kan, nigba t'awọn mii sọ pe awọn ni ìmọ nipa rẹ ni.

Ẹ jẹ ki a wo bayii pe ẹnikan da jokoo nile ọtí t'awọn eeyan ti pọ lalẹ ọjọ Ẹti kan, ki ẹni ti o n ta ọti wa ri ẹni naa nibi ti o jokoo si, ki o si lọ bẹrẹ si ni ba a sọrọ níbẹ.

Ẹni ti o n ta ọti yii ti ba a onibara to da jokoo yii sọrọ debi pe o ti gbagbe pe ọrẹ rẹ to n reti gan an ko tii de.

Gurit Birrbaum to jẹ Ọjọgbọn nipa ihuwasi ẹda ni fasiti Reichman sọ pe "ti ẹnikan ba ba ẹ sọrọ, o maa jẹ ki o ri ara rẹ ju bi o ti wa lọ."

Lori apẹẹrẹ ile ọti ti a ti sọ nipa rẹ, onibara ti ẹni to n ta ọti n ba a sọrọ ni ibasepọ pẹlu ẹlomiran.

"Titage pẹlu ajeji le ṣe iranwọ fawọn eeyan ninu ibaṣepọ wọn pẹlu ololufẹ wọn"

Birnbaum ni biba ẹlomiran sọrọ kii ṣe tuntun.

"Nigba t'awọn eeyan ba bẹrẹ si ni ranti nipa awọn to ti b'awọn sọrọ, ìyẹn ko tumọ si pe o le ṣakoba fun ìbáṣepọ̀ ti wọn ni pẹlu ẹlòmíràn."

Ọjọgbọn Birnbaum ni titage pẹlu ajeji le ṣe iranwọ fawọn eeyan ninu ibaṣepọ wọn pẹlu ololufẹ wọn.

Amọ, o si tun le ba nnkan jẹ bakan naa.

Ọjọgbọn Birnbaum sọ pe awọn eeyan ni lati kiyesara pẹlu ẹni ti wọn ba n tage ki o to di nnkan mii.

O ni kò wọ pọ ki oge tita di pe kawon eeyan maa ṣe iṣekuṣe pẹlu ẹni ti kii ṣe ololufẹ wọn.

A ko mọ bi a se n tage, ni a se wa ni apọn - Akọ ẹgbẹrun meje

Bi oge tita ṣe ni anfani ninu to, ọpọ eeyan lo sọ pe awọn ko mọ ọ ṣe.

Nigba ti wọn bi ẹgbẹrun meje ọkunrin to n lo ẹrọ Reddit leere, wọn ni ara idi tawon si fi wa ni apọn ni pe awọn o mọ bi wọn ṣe n tage.

Amọ, ohun ti eeyan le kọ ni oge tita.

Lẹyin wakati mẹta ti won ṣe idanilẹkọọ fawọn eeyan kan lori oge tita ati fifi igboya sọrọ, maaki gidi ni wọn gba.

Ọna mii lati ta oge ni nipa wíwọ aṣọ nla ati wiwo ẹni ti o fẹ ba sọrọ loju.

Aworan ololufe meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Gbangba ni awọn ọkunrin ti maa n tami oge amọ ọgbọọgbọn lawọn obinrin fi n se tiwọn”

Ati ọkunrin ati obinrin lo le lo ọna yii lati ta oge pẹlu ẹni ti wọn ba fẹ.

Ọjọgbọn T. Joel Wade onimọ nipa ihuwasi ẹda ti fasiti Bucknell ni America sọ pe "kii ṣe pe ti o ba ri ẹni to rẹwa naa ni wa a fẹ ba a sọrọ o."

O ni iru nnkan bayii gbọdọ wa lati ọkan ni, kii kan ṣe ohun ti eeyan le ki giri se.

Ọjọgbọn onimọ nipa ihuwasi ni fasiti St. Mary ni Canada l, Maryanne Fisher ṣalaye pe, iyatọ to wa laarin bi awọn ọkunrin ati obinrin ṣe n tage ni pe ni gbangba l'awọn ọkunrin ti maa nṣe ti wọn eleyii ti gbogbo eeyan maa ri.

Amọ, ọgbọn lawọn obinrin fi maa ṣe ti wọn.

Awọn ọkunrin maa n fi karamọ kun ọrọ oge tita ni ti wọn.

Aworan ololufe meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Awọn olokowo mii gan an maa n lo oge tita lati ta ọja"

Awọn ọkunrin le ri obinrin to n b'awọn ṣe ọrẹ lasan an gẹgẹ bi pe o nifẹ wọn ni.

Ọjọgbọn Fisher ni fun apẹẹrẹ, ẹrin rinrin ni Canada jẹ ohun to wọ pọ.

Amọ, ọpọ ọkunrin maa n ri awọn obinrin to n b'awọn rẹrin bii wi pe o nifẹ awọn ni.

Awọn olokowo mii gan an maa n lo oge tita yii lati ta ọja.

Fisher ni awọn kan fi awọn obinrin sita ile ounjẹ lati maa ki awọn onibara.

O ni awọn kan ti pe ẹjọ ni Amerika bayii lẹyin t'awọn obinrin kan sọ pe awọn ọga awọn sọ pe kawon maa rẹrin b'awọn onibara sọrọ, amọ, awọn onibara naa wa ri bi ẹni pe awọn nifẹ awọn ni.

O yẹ ki a le beere bo ya ẹni to n ta ọti ti a kọkọ sọ nipa rẹ n dẹnu ifẹ kọ onibara rẹ ni tabi o kan n ṣiṣẹ rẹ ni.