Àwọn ọmọ Yoruba tó ń ta ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù, ọbẹ̀ ẹ̀gúsí àti mọ́í-mọ́í gba àmì ẹ̀yẹ nílẹ̀ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, JODI HINDS
- Author, By Danai Nesta Kupemba
- Role, BBC News
Lara awọn ounjẹ aladun ti awọn eeyan n jẹ nile ounjẹ ilẹ adulawọ kan to wa ni aringbungbun ilu London ni ahọn maalu.
Wọn n ṣe ahọn maalu naa bii ẹran suya nile ounjẹ ọhun ti orukẹ rẹ n jẹ Akoko, eyii to gba ami ẹyẹ ‘Michelin star.’
Ami ẹyẹ Michelin yii ni wọn maa n fun awọn ile ounjẹ to dangajia kaakiri agbaye, latari pe ounjẹ ti wọn n se dun, o si jọju nigbese.
Ile ounjẹ Akoko yii si wa lara eyii ti awọn eeyan n wa julọ lẹyin ti ile ounjẹ naa ati ile ounjẹ meji miran gba ami ẹyẹ Michelin lọdun to kọja.
Ọga agba ile ounjẹ naa, Ayo Adeyemi sọ fun BBC pe awọn ṣẹṣẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni.
Yato si Akoko, ile ounjẹ mii tun n se ounjẹ to dun lagbegbe Fitzrovia, niluu London.

Oríṣun àwòrán, MICHELIN
Adejoke Bakare, ọmọ Naijiria to kọ ara rẹ niṣẹ ase naa gba ami ẹyẹ Michelin niluu Macnhester ninu oṣu yii lẹyin ti ile ounjẹ rẹ, Chishuru, fakọyọ.
Adejoke ni ọmọ ilẹ adulawọ akọkọ, to jẹ obinrin ti yoo gba ami ẹyẹ naa nilẹ Gẹẹsi ati ẹni keji ti yoo gba a lagbaye.
O sọ fun BBC pe “Awọn eeyan ri pe orisun wa ni a n pin nipase ounjẹ wa ni gbogbo igba ti wọn ba ti n jẹun lọdọ wa.”
O ni pẹlu ami ẹyẹ naa, boya Michelin yoo bẹrẹ si n fun awọn olounjẹ ni ami ẹyẹ ọhun ni Afrika.
Lọwọ yii, ile ounjẹ kan ṣoṣo lo tii gba ami ẹyẹ Michelin ni Afrika, iyẹn lorilẹ-ede South Africa.
Adejoke sọ siwaju si pe Chishuru ati Akoko n ṣafihan pe awọn eeyan mọ iyi ounjẹ adulawọ niluu London.

Oríṣun àwòrán, JODI HINDS
Lara awọn ounjẹ ilẹ adulawọ, paapaa ounjẹ Naijiria ti Michelin ri ko to kede ami ẹyẹ naa ni irẹsi jọlọọfu, ọbẹ ẹgusi, mọimọi atawọn ounjẹ mii.
Kii ṣe ilẹ Gẹẹsi nikan lawọn eeyan ti fẹran awọn ounjẹ wọnyii.
Ṣaaju ni oṣere tiata ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan, Will Poulter, ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu Michelin, latari bi ko ṣe naani ounjẹ ilẹ adulawọ.
O ni “Awọn eeyan ko bu iyi to yẹ fun ounjẹ to wa lati ilẹ adulawọ, to fi mọ awọn alase to jẹ eeyan dudu.”
Alase ọmọ orilẹ-ede Benin kan to n fi France ṣebugbe, Georgiana Viou sọ pe nnkan ti n yipada bayii lori oju ti wọn fi n wo ounjẹ ilẹ adulawọ lagbaye.
O ni “Ni bayii ti ile ounjẹ Akoko ati Chishuru, to n ta ounjẹ ilẹ adulawọ nikan ṣosọ ti n gba ami ẹyẹ n tumọ si pe nnkan ti n yipada.”
“Mo ni afojusun lati lati ṣi ile ounjẹ tuntun kan ti yoo maa ta ounjẹ ilẹ adulawọ nikan ṣoṣo.”

Oríṣun àwòrán, JODI HINDS
Ẹni to ni ile ounjẹ Akoko, Aji Akokomi, to jẹ ọmọ Naijiria lọ silẹ Gẹẹsi ni nnkan bii ogun ọdun le diẹ sẹyin.
O ni oun fi awọn ọmọ Naijiria sọkan lo mu ki oun da ile ounjẹ to n se ounjẹ Naijiria silẹ okeere.












