Ebi lu irinwó èèyàn pa, èso Àgbáyun àti ewé lásán làwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń jẹ lẹ́yìn ogun Tigray

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọwọ yii, o le ni irinwo eeyan ti ebi ọpagba ti pa ku lagbegbe Tigray, lorilẹ-ede Ethiopia latari ogun abẹle to waye nibẹ.
Yatọ si awon ti ebi pa ku, ẹgbẹgbẹrun akẹkọọ lo ti fi ile ẹkọ silẹ lọna ati maa wa ounjẹ ti wọn yoo jẹ kiri.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ewe lasan lọpọ awọn eeyan naa n jẹ bayii, nigba ti awọn mii n fi eso ‘wild berries’ bọ ara wọn.

Oríṣun àwòrán, getty images
Nigba ti ikọ ileeṣẹ iroyin BC ṣabẹwo si agbege naa, ogun abẹle ọhun ti ba nnkan jẹ gidi nibẹ.
Olori ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan nibẹ, Yemane Teklay ṣalaye fun BBC pe ọpọ akẹkọọ ni ko kawe mọ.
O ni “Gẹgẹ bii ẹ ṣe ri, awọn alatako ni wọn dana sun ile ẹkọ yii, eyii to mu ko ṣoro lati kẹkọọ nibi.”
“Ebi n pa awọn akẹkọọ, wọn si ti dana sun ile ẹkọ... o dara lati kawe lootọ, ṣugbọn oorun n pa wa.
“Nigba ti mo n ṣiṣẹ nibi gẹgẹ bii adari, ọrọ naa ba inu mi jẹ gidi; awọn to ṣi ku sile ẹkọ gan, inu inira ni wọn ti n kẹkọọ ọhun.
Ọkan lara awọn akẹkọọ naa to jẹ ọmọ ọdun mejila, Freya sọ fun BBC pe ori okuta lawọn n joko le nitori ko si aga ijoko.
Freya sọ pe “Awọn akẹgbẹ wa ti fi iwe kika silẹ, wọn ti n lọ wakusa wura.
“Awa to ku ti a n kawe, eso wild berries ni a n jẹ, laipẹ lai jina, awa naa ṣi maa fi iwe kika silẹ.
Akẹkọọ ọhun sọ pe iwuwasi awọn akẹgbẹ ohun ni kilaasi n fi han pe ebi n pa wọn.
O ni ohun ti wọn maa jẹ ni wọn n fi inu ro ni gbogbo igba kii ṣe ẹkọ ti wọn n kọ wọn.















