Komla Dumor Award 2024: BBC tún ṣetán láti wá ìràwọ̀ akọ̀ròyìn míì ní Africa

Aworan Komla Dumor
Àkọlé àwòrán, Komla Dumor

Ileeṣẹ iroyin BBC tun ti ṣe ifilọlẹ ami ẹyẹ idanimọ akọroyin to dantọ fun ọdun 2024.

Ami ẹyẹ yi ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ ni iranti akọroyin nii Komla Dumor ti pe ọdun mẹsan ti wọn bẹrẹ rẹ bayii.

Awọn akọroyin jakejado ilẹ Africa lo olanfaani lati kopa ninu idije yi ti yoo ṣe afihan akọroyin to kọṣẹmọṣẹ ni Africa.

Oṣu mẹta ni ẹni to ba jaweolubori yoo lo ni olu ileeṣẹ BBC to wa ni London ti yoo si kẹkọ si nipa iṣẹ iroyin.

Lọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹta ni ago mejila ku iṣẹju kan ni gbendeke ti wọn faaye kalẹ lati forukọ silẹ kopa ninu idije naa.

Wọn ṣe idasilẹ ami ẹyẹ yi ni irnati Komla Dumor akikanju akọroyin ọmọ orileede Ghana to jẹ atọkun lori eto BBC World News to dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelogoji ni nkan bi ọdun mẹwaa sẹyin.

Opo Dumor,Kwansema Dumor sọ pe ''inu oun dun si aṣeyọri ati ipa ọkọ rẹ ni BBC''

O ni idile awọn ''dupẹ lọwọ BBC fun iranti ti wọn ṣe fun ọkọ rẹ'' nipasẹ ami ẹyẹ yii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tori naa BBC wa n kesi awọn akọroyin lati forukọ silẹ kpa ninu idije yi lọna ati fi gbe ogo iṣẹ akọroyin ga laarin awọn to n ṣe iṣẹ akọroyin nilẹ Africa.

Yatọ si ẹkọ ti akọroyin yoo kọ kun ẹkọ, ẹni ito ba jaweolubori yoo lanfaani lati rinrinajo jakejado Africa lati ṣisẹ lori iroyin ti wọn ṣe iwadii rẹ ti wọn yoo si gbe safẹfẹ fawọn eeyan Africa.

Lasiko to wa laye, ilumọọka ni Komla Dumor jẹ nipa gbigbe iroyin nipa ilẹ Africa jade nigbe ododo.

BBC ko sinmi ifarajin rẹ nipa itẹsiwaju iranti igbe aye Dumor tori naa ni wọn yoo fi tubọ maa ṣe iranwọ fun awọn akọroyin ilẹ Africa lati le ge iroyin jade nipa ilẹ Africa.

Akọroyin ọmọ orileede Ghana nii Paa Kwesi Asare lo jaweolubori ninu idije ti ọdun to kọja.

Ọmọ ilẹ kanna lo jẹ pẹlu Komla Dumor.

Lasiko ti wọn fun lanfaani yi o rinrinajo lọ si Kenya lati lọ gbe iroyin jade nipa awọn ọkada ilẹ naa ''boda boda'' ti wọn yoo maa lo ina ẹlẹktriki dipo bẹntiroo tabi epo disuu.

Ọga agba ileeṣẹ iroyin BBC Liliane Landor sọ pe ''inu mi dun lati ri awọn irawọ akọroyin ti ami ẹyẹ yi ṣafihan wọn lorukọ Komla Dumor''

Awọn to ti gba ami ẹyẹ yi kọja ṣaaju:

2023: Paa Kwesi Asare lati Ghana

2022: Dingindaba Jonah Buyoya lati Zambia

2020: Victoria Rubadiri lati Kenya

2019: Solomon Serwanjja lati Uganda

2018: Waihiga Mwaura lati Kenya

2017: Amina Yuguda lati Nigeria

2016: Didi Akinyelure lati Nigeria

2015: Nancy Kacungira lati Uganda