Láàrín Ààrẹ Kenya àti Nigeria, tá a ló rìn ìrìnàjo jùlọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Basillioh Rukanga
- Role, BBC News
Lati igba ti Aarẹ Kenya, William Ruto ati Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti di Aarẹ ni wọn ti n koju awọn eebu lori bi wọn se n rin irinajo lọ si oke okun.
Awọn aarẹ mejeeji ni ọpọ eeyan ti bu ẹnu atẹlu lori iye ti wọn fi n rin irinajo lasiko ti orilẹede wọn koju kudiẹkuidẹ eto ọrọ aje.
Ileeṣẹ iroyin Kenya, the Standard, fun Aarẹ Ruto ni orukọ ‘Aarẹ to n fo’. O ni Aarẹ nifẹ pupọ si bi o ṣe n fo lasiko ti anfani ba ti yọ lati fo ” pẹlu bi ọwọngogo se gbodo ni orilẹede rẹ.
Ni oṣu to kọja, Aarẹ Tinubu rin irinajo mii lọ di ilẹ Yoorupu, Olori ẹgbẹ oṣelu alatako Atiku Abubakar sọ lori ayelujara pe orilẹede Naijiria ko nilo arin irinajo gẹgẹ bii aarẹ.
O bu ẹnu atẹlu bi aarẹ se n rin irinajo lasiko ti awọn ọmọ Naijiria n koju eto aabo to mẹyẹ
Awọn aarẹ nilo lati rin irinajo lọ kopa ninu ipade awọn olori ilu, mu ibaṣepọ pẹlu awọn orilẹede damọran. Eyi ṣe koko fun ọrọ oṣelu bakan naa fun eto ọrọ aje.
Sugbọn awọn kan ti tọka si pe Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Tanzania to di oloogbe, John Magufuli ko fi igba kankan rin irinajo kuro ni ilẹ Afrika ni ọdun mẹfa to lo gẹgẹ bii Aarẹ.
'Ifẹ tara ẹni'
Onimọ nipa ilana oke okun lorilẹede Kenya, Ọjọgbọn Macharia Munene ni otitọ ni pe awọn iriajo kan se koko sugbọn awọn yooku lo jẹ pe aṣedanu.
“A ni awọn aarẹ to nifẹ lati wa lori ofurufu...Pupọ awọn irinajo yii lo jẹ ife inu, ko ki ṣe fun ilu,” o sọ fun BBC.
Aarẹ Ruto ati Aarẹ Tinubu ati awọn agbẹnusọ gbelẹyin awọn irinajo yii pe o ṣe koko lati ran orilẹede lọwọ lati koju awọn iṣoro to wa niwaju eyi ti wọn ko bi ara si.
Laarin oṣu mẹjọ ti Aarẹ Tinubu ti bẹrẹ iṣejọba rẹ, O ti rin irinajo mẹrinla, ti Aarẹ Ruto si ti rin irinajo aadọta lati ọdun 2022 to di aarẹ.
Ti a ba n fi we Aarẹ to kogba wọle, Uhuru Kenyatta, ẹni to rin irinajo kan ninu oṣu kan lasiko to wa iṣejọba.
Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, ni ko fi fẹ si iyatọ laarin irinajo to rin pẹlu ti Aarẹ Tinubu.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn olori orillẹede agbaye naa rin irinajo sugbọn Aarẹ ati Aarẹ Tinubu ni ẹnu kun ju pẹlu ibeere pe se irinajo naa se koko.
Awọn aarẹ mejeeji jọ wa ni ilẹ Yooropu ni ipari oṣu to kọja – Ruto lọ si Italy fun ipade Italy-Afrika nigba Aarẹ Tinubu si irinajo bonukẹlẹ ti ko a ko le salaye lọ si ilẹ France, to jẹ igba kẹta to ti lọ si orilẹede naa lati oṣu karun un ọdun to kọja.
Ninu oṣu kẹfa ọdun 2023, ọsẹ kẹta lẹyin to di aarẹ, Tinubu rin irinago ọlọjọ meji lọ si orilẹede France fun ipade . Saaju lo ti kọkọ lọ sibẹ lati sinmi ati gbaradi fun gbigba agbara lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bii Aarẹ
Lati Paris o lọ si ilẹ UK fun ipada pẹlu aarẹ to kogba wọle, ti oun na rin irinajo funisinmi lẹyin eto idibo. Lẹyin oṣe kan, Tinubu lọ si Guinea-Bissau fun ipade pẹlu awọn ECOWAS, ko to morile Nairobi.
Ni oṣu kẹjọ, o lọ Benin, ni oiṣu kẹsan an o lọ India, United Arab Emirates ati Ilẹ Amẹrika fun ipada ajọ agbaye ko to pada si Paris.
Ijọba apapọ Naijiria ti salaye pe awọn irinajo yii se koko lati mu okowo wọle lati oke okun.
“Ni gbogbom irinajo ti mo gunle, ọrọ mi si awọn oludokowo ati awọn onisowo ni ko yi pada. Nigeria setan lati ba wọn dowopọ.” Aarẹ Tinubu sọ ninu ọrọ rẹ fun ọdun tuntun.
Irinajo Aarẹ Ruto lati igba to ti di Aarẹ lọdun 2022 lo lagbara. Lati oṣu kẹsan an ọdun naa titi wọ oṣu kejila ọdun to kọja, o ti rin irinajo ni ẹmeji ni oṣu. Ni oṣu karun un ọdun 2023, o rin irinajo ni igba marun un. O ti lọ si orisirisi ilẹ adulawọ, yooropu, Amẹrika fun ipade.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eyi ki i ṣe nipa awọn irinajo nikan sugbọn nipa iye ti wọn n na.
Tinubu ti san owo toto 3.4bn naira lori irin ajo abẹlẹ ati oke okun laarin oṣu mẹfa to di aarẹ- to le Ida mẹrinlelogoji iye owo ti ijọba seto fun eto isuna ọdun 2023., Punch salaye, gẹgẹ GosSpeed ileeṣẹ to n ṣe iwadi bi ijọba ṣe n na owo.
Ni Kenya, agbẹnusọ ijọba kọ lati da BBC lohun nipa ibeere nipa irinajo Aarẹ Ruto bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ati agbẹnusọ rẹ ti ni ko si nnkan to buru nipa rẹ.















