Ẹ̀mí mẹ́wàá bọ́, méje farapa torí eré àsájù lásìkò òjò tó fá ìjàmbá ọkọ̀ lọ́na Eko sí Abeokuta

Oríṣun àwòrán, NEMA
Isẹlẹ ijamba ọkọ gbẹmi eeyan mẹwaa loju ọna opopona morosẹ Eko si Abeokuta.
Agbegbe afara Kere ni ijọba ibilẹ Ewekoro ni isẹlẹ naa ti waye ni oni, Ogunjọ oṣu keji ọdun 2024, lẹyin ti ọkọ akero kan lọ kọlu ọkọ nla tirela to n ko ẹru.
Apapọ eeyan mẹtadinlogun lo wa ninu ọkọ akẹro Mazda alawọ funfun pẹlu nọmba idanimọ SMK808YD nigba to kọlu ọkọ nla tirela to ko ẹru, eyi ti ko si ni nọmba idanimọ .
Eeyan mẹwaa, ọkunrin mẹfa ati obinrin mẹfa lo ba isẹlẹ naa lọ, ti eeyan meje mii si farapa yanayana.
Ajọ FRSC ti ipinlẹ Ogun, ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ Florence Okpe fi lede fun awọn akọroyin salaye pe, ere asapajude ati gbigba ọna ọlọna lo fa ijamba ọkọ mejeeji.
O tẹsiwaju pe, ajọ naa ti ko awọn eeyan to farapa lọ si ile iwosan ijọba to wa niluu Ijaye, ti wọn si gbe awọn to padanu ẹmi wọn lọ si ile gbokusi ni Lantoro niluu Abeokuta.
Ọga agba fun ajọ FRSC wa rọ awọn awakọ lati ri daju pe wọn tẹle ilana ati ofin irinajo ti ijọba gbe kalẹ lati dẹkun ijamba ọkọ to n waye.
Bakan naa lo tun rọ wọn lati yago fun sisa ere a’sapajude loju opopona.
O wa ba awọn mọlẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn kẹdun pe Ọba yoo duro ti wọn.

Oríṣun àwòrán, NEMA















