Ajínigbé jí ọ̀pọ̀ ẹbí tó ń gbé òkú bọ̀ láti Eko sí Enugu, wọ́n ń bèèrè N50m owó ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, COLLINS UGWUANYI
Iroyin kan to n ja kiri lori ayelujara lo salaye pe awọn ajinigbe ji oku ọkurin kan ati awọn mọlẹbi rẹ gbe, lasiko ti wọn n gbe oku naa lọ si Ameze Owerre nipinlẹ Enugu.
Israel Ugwuanyi, ẹni aadọta ọdun lo jẹ onisowo, to si jade laye ni ọjọ Aiku.
Awọn mọlẹbi rẹ n rin irinajo lati Eko lọ Enugu fun eto isinku lasiko ti awọn agbebọn kọlu wọn, ti wọn si ji wọn gbe, gẹgẹ bii ọmọ oloogbe se salaye fun BBC .
Lati igba ti iroyin naa ti jade naa, ọpọ ti n beere lori ayelujara pe se oku nikan ni wọn jigbe tabi wọn gbe oku ati awọn eeyan to wa pẹlu rẹ.
Ohun taa mọ ree nipa isẹlẹ naa
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"A pe awọn arin irinajo pe ki wọn ma gbe oku bọ fun isinku lọjọ Aiku sugbọn ko si ẹnikẹni to gbe ipe naa"
Aburo Israel, Collins Ugwuanyi sọ fun BBC pe, ẹgbọn oun ni ileeṣẹ itaja bata nipinlẹ Anambra, ko to lọ si ipinlẹ Eko lati wa owo kun owo.
O ni ko pẹ to de Eko lo dubulẹ aisan fun ọdun marun un.
“Fun ọdun marun un lo fi wa ni idubulẹ aisan nipinlẹ Eko, to si ni lati ta gbogbo dukia to ni.
“Nigba ti wọn ransẹ pe mi pe aisan naa ti lagbara si, ti wọn si tun pe mi pe o ti jade laye .
“Nitori pe o se aisan ti pẹ, a sure lati tete gbe sin.
Nigba ti mo pe awọn aburo mi ti wọn rin irinajo, wọn sọ fun mi pe awọn ti wa ni agbegbe Oji River.
“Aburo ọkunrin mi keji, Boniface sọ fun mi pe oun ti n pe awọn arin irinajo pe ki wọn ma gbe oku bọ fun eto isinku lọjọ Aiku sugbọn ko si ẹnikẹni to gbe ipe naa.
“Emi naa pe wọn sugbọn ko si ẹnikẹni to dami lohun.
"Ko pẹ ni ipe kan wọle, to si ni ọmọ ologun ni oun ati pe o da bi pe awọn mọlẹbi mi ti ko sọwọ awọn ajinigbe nitori o ri ọkọ wọn ni oju opopona.
“Mo beere lọwọ ọmọ ologun naa pe nibo lo ti ri foonu wọn to fi n pe mi, o ni oun ri ninu ọkọ ti oku aburo mi wa ati pe ko si ri ẹnikẹni nibẹ.
“Mo pe pada lati bere pe boya wọn lọ se igbọnsẹ ninu igbo sugbọn o ni rara. O ni ki ma bọ ni Umuokar nibi to gbe oku ati ọkọ si.
"Mo sọ fun pe ko gbe lọ si Ileeṣẹ ọlọpaa sugbọn o ni ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati gba oku naa.
“Mo bẹ ọmọ ologun naa lati gbe oku naa lọ si ile igbe oku si, pe ma wa ni ọjọ keji.
Collins ni otitọ pe wọn ji awọn eeyan gbe ninu mọlẹbi oun.
“Eeyan mẹta ni wọn ji gbe, ọkunrin kan, obinrin kan ati awakọ to wa ọkọ naa.”
Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Ileeṣẹ BBC kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ Enugu, Charlse Ndukwe, to si ni wọn ti fi isẹlẹ to ileeṣẹ ọlọpaa leti pe awọn ajinigbe gbe eeyan mẹta, ti wọn si fi oku silẹ.
“A ko mọ gbogbo nnkan to waye sugbọn pẹlu bi nnkan se n lọ lorilẹede Naijiria, ọpọ nnkan lo le waye.
“N ko le sọrọ pupọ nitori iwadii wa n lọ lọwọ.”















