EFCC mú gómìnà àná ní Kwara lórí ẹ̀sùn màgòmágó N10bn, PDP ṣe ìwọ́de pé ìwà ìfìyàjẹni ni
Kí ni ìdí tí EFCC ṣe tí Abdulfatah Ahmed mọ́lé?

Oríṣun àwòrán, BBC/Abdulfatah Ahmed
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP nipinlẹ Kwara ṣe ifẹhonuhan lọ si ileesẹ ajọ to n gbogun ti iwa jìbìtì, ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, (EFCC), to n bẹ niluu Ilọrin lẹyin ti wọn nawọ gan gomina ana nipinlẹ naa
Abdulfatah Ahmed lo ti wa ni akata ajọ EFCC fun ifọrọwanilenuwo lori billionu mẹwaa naira ti wọn lo gbe gba ibomii lọ lasiko ijọba rẹ gẹgẹ bi gomina.
Abdulfatah Ahmed, ẹni ti ọpọ tun mọ si Maigida, lo jẹ gomina ipinlẹ Kwara fun sa meji gbako labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP laarin ọdun 2011 si 2019.
Lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun ọsẹ yi ni gomina tẹlẹ ri ọhun yọju si ile isẹ ijọba naa lati wi tẹnu rẹ lori ẹsun si sowo ilu mọkumọku ti wọn fi kan an.
"Ijọba Kwara ati EFCC lẹdi apo pọ lati fi Ahmed si ahamọ, ko le darapọ mọ APC dandan ni"
Iwọde alaafia ọhun lo waye niwaju ọfiiṣi ajọ EFCC, niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti n pariwo pe ajọ naa ti rufin, latari pe gomina tẹlẹ naa wa ni akoso wọn kọja ọjọ meji to wa ninu iwe ofin ilẹ wa.
Wọn salaye pe ni se ni o yẹ ki wọn gbe e lọ sile ẹjọ gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ti laa kalẹ.
Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, ni Kwara, Ọgbẹni Oluṣọla Adewara Shollyment, to ṣọrọ niwaju ọga ajọ EFCC, fẹsun pe ijọba ipinlẹ Kwara ati ajọ naa pe wọn lẹdi apo pọ lati fi Maigida si ahamọ ki ara rẹ le rọ, ti yoo si yi ipinnu rẹ pada lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC,
O tẹsiwaju pe ohun to ṣokunfa ifẹhonu yii ni pe, gbogbo awọn n beere fun ki wọn tu gomina tẹlẹ ọhun silẹ ni kiakia nitori pe ẹgbẹ PDP tako bi wọn ṣe fi si akata wọn.
Bakan naa lo ni awọn ti gbọ pe EFCC, ti gbe iwe kan siwaju Ile ẹjọ pe ki wọn lọ fi gomina tẹlẹ ọhun pamọ ṣọgba ẹwọn ṣugbọn kọọtu ko gba si wọn lẹnu, ti wọn si n ṣe idajọ lọwọ ara wọn nipa fifi si ahamọ arawọn.


Koko lara Maigida le lákàtà wa - EFCC fèsì
Nigba to n fesi, ọga ajọ EFCC, Michael Nzekwe ni ofin ni wọn fi gbe ajọ EFCC kalẹ tawọn si n tẹle ofin ọhun bi wọn ṣe gbe e kalẹ.
O sọ pe, fun idi eyi awọn fi gomina tẹlẹri naa si akata awọn ko le ran awọn lọwọ lori iwadii awọn ni.
O wa fidi rẹ mulẹ pe, ko si oun to ṣe afurasi naa lakata awọn pe koko lara rẹ le ati pe agbẹjọro rẹ wa pẹlu rẹ lọdọ awọn.
Lori ẹsun wi pe ajọ EFCC ati ijọba lẹ di apo pọ lati fa afurasi naa si ẹgbẹ oṣelu APC nipaṣẹ fi fẹsun kan an, BBC Yoruba ba alukoro ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara sọrọ, Alhaji Fọlaranmi Aro lati mo iha ti ẹgbẹ naa kọ sii.
O ni kosi laakaye ninu ọrọ naa, wipe gbogbo eeyan to ba di ipo mu ri, igbakuugba ni wọn le ransẹ sii lati wa wi tẹnu rẹ.
O fi kun un pe, lotitọ ni ẹgbẹ oṣelu o gba ole, o gba ọlẹ sugbon ti awọn ba ti ẹ fẹ faa wọ ẹgbẹ, dandan kọ ni ki awọn maa fi ọlọpaa tabi EFCC lee kiri nitori pe, "A kii tile ẹjọ de sọrẹ".
"Maigida yoo foju ba ileẹjọ lọjọ Ẹti"
EFCC ti jẹ ko di mimọ pe Gomina ana yoo foju ba ile ẹjọ fun ẹsun pe o yi owo ilu toto billionu mewaa nairsi ibo mii lasiko rẹ gẹgẹ bi gomina.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin abẹle ṣe gbe jade pe Gomina ana yoo farahan niwaju ileẹjọ giga to wa niluu Ilorin lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu keju ọdun 2024.
Agbẹnusọ fun gomina tẹlẹ naa, AbdulWahab Oba fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni pe Abdulfatah wa ni ahamọ ajọ EFCC.
"EFCC ransẹ pe Dokita Ahmed, o si dawọn lohun gẹgẹ bi o ṣe ma sẹ.
"Nigba ku gba ti wọn ba a pe lati wi tẹnu rẹ lori nnkan to jẹ asiko rẹ gẹgẹ bi gomina, ko ki n fi ṣere rara."















