Ìwádìí rèé lórí ìdí tí ọlọ́pàá ṣe gbé Alága ẹgbẹ́ Labour, Abure

Abure ati Labour Party

Oríṣun àwòrán, Collage

Ọlọpaa, Labour Party tabi ikọ Abure ko tii sọ idi ti wọn fi gbe alaga ẹgbẹ"

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo lagbegbe guusu guusu ilẹ naa ti fi pampẹ ofin mu alaga ẹgbẹ oṣelu alatako Naijiria Labour Party tii ṣe Dokita Julius Abure.

Ni Ọjọru lawọn agbofinro mu ni ilu Benin City tii ṣe olu ili ipinlẹ Edo, ki wọn to gbe silẹ ni owurọ ọjọbọ.

Kaakiri oju opo ayelujara la ti ri aworan ati fọnran fidio to ṣe afihan bi awọn ọlọpaa ṣe ge Abure sinu ọkọ wọn.

Awọn akọroyin lagbegbe naa sọ pe agbẹnusọ ọlọpaa lẹkun karun Tijani Momoh, fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn mu Abure.

Ko ti daju idi ti wọn fi mu Abure lati ẹnu awọn ọlọpaa, ẹgbẹ oṣelu Labour Party tabi lati ọdọ awọn ikọ Abure funrarẹ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

"Mimu ti wọn mu awọn adari ẹgbẹ Labour ko sẹyin iwe ẹhonu ti igun Lamidi Apapa kọ"

Amọ iroyin taa ri lati ọdọ awọn ileeṣẹ iroyin labẹle sọ pe mimu Abure ko sẹyin ẹsun to nii ṣe pẹlu igbiyanju lati ṣekupaniyan ati awọn ẹsun mii.

Agbẹnusọ ẹgbẹ Labour Party, Obiora Ifoh, naa fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni wọn mu Abure gẹgẹ bo ṣe sọ ninu atẹjade kan.

O sọ pe bẹẹ naa ni wọn mu alaga ẹgbẹ Labour Party ni ipinlẹ naa, Kelly Ogbaloi.

O ni idibo awọn aṣoju ẹgbẹ naa to waye ni ọjọ Iṣẹgun lọ ni irọwọrọsẹ ṣaaju idibo abẹnu ẹgbẹ ti yoo waye lọjọ Ẹti.

Ifoh fẹsun kan pe mimu ti wọn mu awọn adari ẹgbẹ naa ko sẹyin iwe ifẹhonuhan kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ igun Lamidi Apapa kọ .

O ni wọn mu awọn adari ẹgbẹ yi lati le fi da eto idibo abẹnu to fẹ waye ru ki ẹgbẹ ma ba lanfaani lati kopa ninu idibo Gomina to n bọ niwaju.

Ninu ọrọ rẹ igbakeji alaga ẹgbẹ naa, Dokita Ayo Olorunfemi ninu fidio kan sọ pe ko si iru ihalẹ tabi idunkoko mọni to le wu ko waye, ti yoo mu kawọn ma tẹsiwaju pẹlu eto bi ijọba yoo ṣe bọ sọwọ Labour Party ni ipinlẹ naa.

Ki lo ti sẹlẹ saaju?

Dokita Julius Abure to jẹ alaga ẹgbẹ LP ti n koju awọn ipenija kọọkan lẹnu lọọlọ yi.

Eyi to waye kẹyin ni eleyi to ṣẹlẹ lẹyin ti o ni ki akapo ẹgbẹ Oluchi Opara lọ rọọkun nile lori pe o fẹsun kan an (Abure) pe o yiwe bẹẹ lo si ji owo ti ẹgbẹ ko jọ lasiko idibo aarẹ ọdun 2023.

Abure ati ẹgbẹ tako ẹsun yi sibẹ wọn tẹsiwaju lati ni ki akapo lọ rọọkun nile.

Akapo yii naa ko si dakẹ lori ọrọ yii, to si n tẹnumọ pe Abure ni lati wa ṣe iṣiro gbogbo owo iranwọ Naira ati dọla ti ẹgbẹ ko jọ lasiko idibo.

Lọsẹ to kọja ni ẹgbẹ ni ki akapo naa lọ rọọkun nile fun odindi oṣu mẹfa gbako.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Ohun taa gbọ ni pe nkan bi biliọnu Naira kan le diẹ ni ẹgbẹ gba gẹgẹ bi owo iranwọ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ ati nibi owo fọọmu ti wọn ta fawọn to fẹ dije dupo lasiko idibo aarẹ ọdun 2023.

Ẹgbẹ Labour naka alebu si awọn to lo alaga igun ẹgbẹ naa kan Lamidi Apapa gẹgẹ bi awọn to n lo Opara lati fi da ẹgbẹ ru.

Ẹwẹ awọn ọmọ Naijiria ti n sọ tẹnu wọn lori iṣẹlẹ yii.

Bawọn kan ṣe n beere pe ki lo ṣe gaan ti wọn fi mu lawọn mii n ṣe eemọ pe o ṣe wa jẹ iru ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni iru omi abuku yi n ta si lara.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4