Ẹ wo bí 'Candle Night' tí àwọn òṣèré ṣe fún Sisi Quadri nílùú eko ṣe lọ

Sisi Quadir

Oríṣun àwòrán, bbc

Awọn akẹẹgbẹ ati ololufẹ gbajumọ oṣere, Quadri Oyebamiji, ti ọpọ mọ si 'Sisi Quadri' ti sọ iriri wọn ati ohun ti awọn ko ni le gbagbe nipa oloogbe naa.

Awọn ọrọ naa lo jade nibi ti awọn ọrẹ ati ololufẹ oloogbe ọhun ti ṣe ayẹyẹ iranti ‘candle night procession’ fun.

Agbegbe Alagbado nipinlẹ Eko ni eto naa ti waye ni alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta, ọdun 2024.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kinni, oṣu Kẹta ọdun 2024, ni Sisi Quadri ku, lẹni ọdun mẹrinlelogoji.

Aṣọ dudu ti wọn ya aworan oloogbe si ni awọn to kopa nibẹ wọ, ti awọn kan lara wọn si gbe patako ti wọn ya a si pẹlu oriṣiriṣi akọle lati fi ibanujẹ wọn han.

Ile itura kan ni wọn ti kọkọ korajọ nibi aago marun-un irọlẹ lati ṣe eto adura, ko to o di pe wọn bọ si igboro nibi ti wọn ti rin fun ọpọlọpọ iṣẹju, pẹu abẹla titan lọwọ wọn.

Olakunle Afuwape, ti ọpọ mọ si Lambebe sọ pe eeyan daadaa ni oloogbe ọhun.

Lambebe ni Sisi Quadri ti ṣe ileri lati ra irẹsi ti oun yoo pin lasiko awẹ awọn Musulumi to n bọ.

O ni “A wa nibi ti a ti n ya fiimu ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, o ni oun maa ra irẹsi apo mẹta ti oun maa pin fun awọn eeyan ninu awẹ, ẹ wa wo Eledumare, awẹ yẹn ko wa ba laye.

“O ni oun maa ha irẹsi, oun maa ha gari, nitori pe ebi n pa awọn eeyan, pe oun fẹ ṣaanu fun awọn eeyan.

“Ẹni to wa sọ nnkan bẹyẹn, Ọlọrun wa ni asiko rẹ ti to.”

Lara awọn gbajumọ osẹre to tun wa nibi ẹyẹ ikẹyin naa ni Bidemi Kosoko, Yomi Fabiyi, ati awọn mii.

Sisi Quadri maa n ra oogun fun mi to ba rẹ mi - Madam No Network

Oṣere tiata Yoruba, Kudirat Soremi, ti ọpọ eeyan mọ si Madam No Network naa ni iku Sisi Quadri dun oun denu egungun.

Madam No Network ni ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin oun ati oloogbe naa.

Gẹgẹ bii ohun ti Madam No Network sọ, oun ati Sisi Quadri maa n fun ara awọn niṣẹ adari ayẹyẹ (MC) ṣe lọpọ igba.

O fi kun pe oloogbe naa jẹ ẹni to n ṣe ikẹ ẹlomiran, koda, o maa n fun oun ni oogun lati lo to ba rẹ oun.

O ni “ti mo ba sọ pe ara n ro mi, a ni mummy, ẹ gba oogun yii ki ẹ lo o, mi o ṣe ni ranti rẹ?

“Ti mo ba n ba eeyan ja nibiti a ti n ya ere, oun lo maa ṣegbe lẹyin mi.

“Nigba mii ti wọn ba fun nibi ti a maa sun si, a ni maami ẹ ko le sun nibi yii daadaa, ẹ jẹ ka maa lọ, a jọ maa kuro nibẹ ni. Ẹni to ba jẹ eeyan, eeyan mi naa ni.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ Ẹti, ọjọ kinni, oṣu Kẹta ọdun 2024, ni Sisi Quadri ku, lẹni ọdun mẹrinlelogoji.

Ọkan lara awọn aburo oloogbe Sisi Quadri, Oyebamiji Muktar, ti ṣalaye fun BBC Yoruba bi irinajo bi iku oloogbe naa ṣe waye.

Okunrin naa sọ pe awọn ti kọkọ gba ipe kan pe o ṣubu nibi to ti n ṣere ori itage lọwọ ki wọn to gbe wale.

O ni “Ni ọjọ kọkandinlogun ni wọn pe wa pe wọn ṣubu nibi ti wọn ti n ṣere itage lọwọ, aburo wa dẹ lọ gbe wọn nibẹ wale.“A gbe wọn lọ sile iwosan, wọn si ṣe ayẹwo fun nibẹ, wọn si sọ pe aisan iba ni wọn ni, wọn si ṣetọju wọn nibẹ.

Yatọ si aisan iba ti Sisi Quadri ni, aburo rẹ ọhun tun sọ fun BBC pe o ni arun ọgbẹ inu amọ wọn n tọju rẹ.

Muktar sọ pe oloogbe naa ṣi fi owo ranṣe si awọn lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii pe ki wọn fi gbẹ kọngadẹrọ ni iranti iya wọn to di oloogbe ni nnkan bii ọdun kan sẹyin.

O fi kun ọrọ rẹ pe oloogbe naa kii sinmi lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ maa n gbiyanju lati ri daju pe o n sinmi, koda, awọn ti fi akoko igba kan pa foonu rẹ ri ki wọn ma baa pe fun iṣẹ.

Taa ni Sisi Quadri, oṣere tiata to di oloogbe?

Sisi Quadri, ẹni ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Tolani Quadri Oyebamiji ni o jẹ ilumọka alawada oṣere tiata Yoruba.

O di ilumọka fun ipa to ko ninu ere sinima to jade lọdun 2004, Seniyan Seranko.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 1979 ni wọn bi Sisi Quadri niluu Iwo nipinlẹ Osun.

O kawa jade ni ile ẹkọ gbogbo nise Poly Iree nipinlẹ Osun.

O fẹ Iyawo, to si ọmọ ọkunrin meji, Olamilekan Oyebamiji and Olamide Oyebamiji, ki ọlọjọ to de.