Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìlànà tuntun tí UEFA gbé jáde fún Champions League

Oríṣun àwòrán, getty images
Idije bọọlu to n waye nilẹ Yuroopu jẹ ọkan gboogi lara eyii to ta lẹnu julọ ti awọn ololufẹ bọọlu si maa n gbadun kaakiri agbaye.
Lati igba ti idije UEFA Champions League ti bẹrẹ lọdun 1955 ni wọn ti maa n ṣe oniruru atunto to ba igba mu si idije ọhun.
Wayi o, ajọ naa tun ti ṣe atunto tuntun fun saa bọọlu ọdun yii, wọn si ni awọn atunto naa yoo ṣe anfani nla fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu, awọn agbabọọlu funra wọn to fi mọ awọn ololufẹ bọọlu pẹlu.

Oríṣun àwòrán, getty images
Wo awọn atunṣẹ tuntun ti yoo waye sawọn ifẹsẹwonsẹ Champions League
Bẹrẹ lati saa yii 2024/2025 lọ, ikọ agbabọọlu mẹrindinlogoji ni yoo maa kopa.
Eyi tumọ si pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu yoo ni ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ ni ipin wọn (group stage.)
Ni saa tuntun ẹgbẹ agbabọọlu kan ko ni maa koju ẹgbẹ agbabọọlu mẹta mii nigba meji ọtọọtọ mọ (home and away), amọ wọn yoo maa koju ẹgbẹ agbabọọlu mẹjọ ọtọtọ.
Lati pin awọn ti wọn yoo dojukọ, UEFA yoo kọkọ pin awọn ikọ ni mẹrin-mẹrin, ti wọn yoo si koju ẹgbẹ agbabọọlu meji ni home and away.’
Igbesẹ yi yoo fun awọn ikọ agbabọọlu laaye lati gbena woju oniruru ẹgbẹ agbabọọlu.
Yoo tun fun awọn ololufẹ bọọlu ni anfaani lati wo ifẹsẹwọnsẹ awọn ikọ to lagbara julọ ni ibẹrẹ idije naa.
Esi idije kọọkan ni yoo sọ ipo ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu yoo wa lori tabili.
Yatọ si awọn atunṣe tuntun yii, awọn atunṣe tuntun mii lo tun wa nipa bi wọn yoo ṣe maa yọ ọwọ awọn ẹgbẹ agbagbọọlu ti ko dangajia lawo idije naa ni gbogbo saa tuntun.
Ninu atẹjade kan lori ikanni ayelujara UEFA, o ni irufẹ nnkankan naa ni yoo waye si idije Europa League ati Europa Conference League.
UEFA sọ pe anfaani ti awọn atunto yii yoo ṣe ni pe yoo jẹ ki awọn ololufẹ bọọlu wo ifẹsẹwọnṣe to pọ daadaa.
Ati pe yoo si tun fun wọn lanfani lati wo ifẹsẹwọnsẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu to dangajia ninu idije naa.














