Ẹ wo bí ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Adedoyin pè tako ìdájọ́ ikú rẹ̀ ṣe lọ ní Akure

Oríṣun àwòrán, RAHMON ADEDOYIN AND TIMOTHY ADEGOKE/FACEBOOK
Ọjọ karun un, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni ile ẹjọ da, lati gbọ ẹjọ kotẹmilọrun ti Ramon Adedoyin pe tako idajọ iku ti ile ẹjọ da fun lẹyin to jẹbi iku Timothy Adegoke.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Akure, nipinlẹ Ondo ni igbẹjọ naa yoo ti waye.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu karun un, ọdun 2023, ni adajọ agba ipinlẹ Osun, Adepele Ojo, ni ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Osun ṣe idajọ iku pe ki wọn lọ yẹgi fun Adedoyin.
Eyi waye lẹyin ti ẹri fi han gbangba pe oun ati awọn kan lo ṣekupa oloogbe Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo to gba yaara si ile itura rẹ niluu Ile-Ife.
Adedoyin lo ni ile itura Hilton ti Adegoke ku si, oun naa tun ni oludasilẹ ile ẹkọ giga Oduduwa University, Ile-Ife.
Akọroyin BBC to wa nile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Akure, jabọ pe igbẹjọ Rahman Adedoyin ko waye.
O jabọ pe ẹjọ kotẹmilọrun bii mẹẹdogun ni wọn pe ni gbogbo igba to fi wa nile ẹjọ, amọ wọn ko pe ti Adedoyin.
Oṣiṣẹ ile ẹjọ kan lo pada fidirẹmulẹ pe wọn ko pe ẹjọ naa nitori pe igbẹjọ to waye lọjọ kan naa pọ.
Ni bayii, ọjọ miran ti wọn ko tii darukọ ni ẹjọ kotẹmilọrun ti Adedoyin pe yoo waye.
Bi ọrọ ṣe bẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke/ Adedoyin
Ṣaaju ni Adegoke, to jẹ akẹkọọ ipele Masters ni fasiti Obafemi Awolowo, OAU, ṣadede di awati lẹyin to lọ sun sile itura Hilton ti Adedoyin da silẹ ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021.
Lẹyin akoko diẹ ti wọn ti n wa ni awọn agbofinro ṣawari oku rẹ ninu koto kan loju ọna atijọ to lọ si ilu Ede, nipinlẹ Osun.
Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe ṣe ni wọn pa oloogbe naa.
Eyi lo mu ki oludasilẹ ile itura naa, Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ kan dero atimọle, ti ọlọpaa si fẹsun mejidinlogun ọtọọtọ kan wọn, lara eyi ti ẹsun ipaniyan wa.
Lasiko igbẹjọ naa ni agbẹjọro oloogbe, Femi Falana, SAN, sọ niwaju adajọ pe ṣe ni awọn afurasi mọọmọ pa oloogbe naa, ti wọn si ju oku rẹ sinu igbo.
Falana ṣalaye pe awọn to pa ọkunrin naa tun wọ inu imulẹ lọ ki akara wọn ma baa tu sepo.
O wa rọ adajọ naa pe ko ṣe idajọ to yẹ fun gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọkunrin naa gẹgẹ bii agbekalẹ ofin.
Ẹwẹ, agbẹjọro awọn afurasi, Yusuf Alli, SAN, fesi pada pe ki ile ẹjọ tu Adedoyin to jẹ onibara oun silẹ nitori ko mọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa, ati pe ko si ẹri kankan to so onibara oun pọ mọ iwa ọdaran ọhun.
Lẹyinorẹyin, adajọ agba Adepele Ojo ṣedajọ iku fun Adedoyin, ati mẹta lara awọn ti wọn jọ fi ẹsun kan wọn.
Idajọ ẹwọn ni awọn yooku gba.
Bakan naa ni adajọ tun paṣẹ pe ki ile itura Hilton ti oloogbe Adegoke ku si, to fi mọ ọkọ Hilux ti wọn fi gbe oku rẹ ju sigbo, di ti ijọba ipinlẹ Osun.
Yatọ si eyi, Onidajo Adepele Ojo tun paṣẹ pe ki wọn o ma a fi awọn dukia awọn ọdaran naa, gbọ bukaata awọn ọmọ ti oloogbe Timothy Adegoke fi saye.














