Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì méjì dèrò ọ̀run níbi tí wọ́n ti fẹ́ gba ìrẹsì ìjọba

Aworan fasiti Nasarawa

Oríṣun àwòrán, Nasarawa State University

O kere tan, akẹkọọ meji ni wọn tẹ pa nibi tawọn akẹkọọ ti to fun raisi ijọba ni ile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ Nasarawa laarọ ọjọ Ẹti niluu Keffi.

Ijọba ipinlẹ naa ṣe agbekalẹ eto pinpin ounjẹ lati ṣe iranwọ fawọn akẹkọọ latari ọwọngogo nnkan to gbode ni Naijiria.

Akọroyin kan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun sọ fun BBC pe awọn akẹkọọ to doloogbe yii wa lara awọn ti wọn to lati gba raisi ijọba naa.

Iroyin sọ pe ero pọju nibi ti ijọba ti n pin raisi ọhun ninu ọgba ile ẹkọ fasiti naa eyi to jẹ kawọn akẹkọọ bẹrẹ si ni ti ara wọn.

Awọn fidio to wa lori itakun ayelujara ṣe afihan bi awọn eeyan ṣe fi agbara ti awọ ẹṣọ eleto aabo danu.

Lẹyin naa ni a gbọ pe wọn fa geeti ibi ti wọn ko ounjẹ naa si lulẹ.

Akẹkọọ kan sọ fun BBC pe ibi ti wọn maa n lo fun ayẹyẹ ikẹkọọgboye jade ni fasiti naa ni ijọba lo lati pin raisi fawọn akẹkọọ.

Akẹkọọ mii sọ pe ijọba ti kọkọ pin raisi ni fasiti ti ijọba apapọ to wa niluu Lafia lọsẹ to lọ, wi pe ile ẹkọ awọn lo kan lọsẹ yii.

O fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ to wa nibẹ ju iye raisi ti ijọba gbe fẹẹ pin lọ.

Akẹkọọ naa sọ pe eyi gan an lo fa ki awọn akẹkọọ maa tẹ ara wọn mọlẹ.

Igbakeji gomina ipinlẹ Nasarawa, Emmanuel Akadeh, to ṣabẹwo si ọgba ile ẹkọ naa sọ pe iṣẹlẹ ọhun ṣeni laanu.

Igbakeji gomina wa ṣeleri wi pe ijọba yoo ṣe iwadii iṣẹlẹ naa lati mọ ohun to ṣe okunfa iku awọn akẹkọọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post