Èèmọ̀ wọ̀lú, afurasí sọ́jà kan gún DPO ọlọ́pàá lọ́bẹ ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Victor Olaiya
Afurasi sọja kan, Suleiman Sadiq ti wa ni akolo Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara bayii lori ẹsun pe o ṣe ikọlu ṣawọn ọlọpaa niluu Sinawu, lagbegbe Ilesha-Baruba to si gun DPO Ọlọpaa lọbẹ.
BBC Yoruba gbọ pe, ọrọ ilẹ kan ti wọn n ja si ni wọn fẹ yanju lagọ ọlọpaa, ṣugbọn ṣe ni Sadiq, to mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa ọhun ko se suuru mọ, ti o ṣi kọlu AS, Okeowo Joel.
A gbọ pe nigba ti ọgagba agọ ọlọpaa naa, DSP Marufu Keji, da si ọrọ ọhun ni Sadiq fa ọbẹ yọ ninu akọ, ti o si gun DPO lọbẹ lọwọ osi.
Ninu atẹjade kan ti alukoro Ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Toun, fi sita, lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni o ti ni awọn yoo ri i daju pe idajọ ododo lawọn ṣe lori ọrọ naa.
O ni, “laaro kutukutu ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹta yii, ni ọkunrin ọmọ ologun ilẹ wa, to n ṣiṣẹ ni Sector 3 Garrison, Mongunu, Maiduguri, Sadiq, fẹsẹ ara rẹ rin wa si ileeṣẹ ọlọpaa niluu Sinawu, Ileṣha Baruba.
"Ọrọ ẹsun ọrọ ija ilẹ lo mu wa ti wọn si ni ki awọn tọrọ kan pada wa lọjọ keji ti i ṣe ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹta yii, ki wọn le ba wọn yanju ẹ.
"Sugbọn ṣe ni Sadiq to ti mu ọti yo, to si wa labẹ idari ọti ọhun tutọ soke to si foju gba a, gbogbo igbiyanju awọn ọlọpaa lati pẹtu si i lọkan lo ja si pabo.
Nisẹ lo fa ọbẹ yọ ninu akọ, ti o si gun ọlọpaa kan ori, bakan naa lo tun gun DPO lọbẹ lọwọ.
"Lẹyin eyi lo fo iganna to si ferege e, sugbọn lẹsẹkẹsẹ ni wọn gba tẹle e, ki ọwọ to pada tẹ ẹ.
A si ti fi panpẹ ofin gbe e, ni ibamu pẹlu ofin”.
O tẹsiwaju pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran, to wa niluu Ilorin, ni wọn gbe Sadiq lọ bayii.
Adetoun, ni agbofinro to gun lọbẹ ti n gba itọju nileewosan bayii, ati pe iwadii si n lọ lọwọ.















