Àrà mi ò rí rí! Ẹ wo ọmọkùnrin ẹlẹ́nu àrà tó le fi ohùn fọn fèèrè láì gbé Sax tàbí Trumpet dání
Àrà mi ò rí rí! Ẹ wo ọmọkùnrin ẹlẹ́nu àrà tó le fi ohùn fọn fèèrè láì gbé Sax tàbí Trumpet dání

bbEmmanuel Adepoju, ti ọpọ mọ si Emma Elenu Ara, jẹ ọdọmọkunrin to ma n fi ẹnu fọn feere lai gbe feere dani.
Ninu ifọrọwanilẹnu ti BBC ṣe fun, Emmanuel sọ fun pe inu eto kan ni oun wa nile ijọsin lọjọ ti ẹbun naa bẹrẹ.
O ni ọrẹ oun kan lo ṣe akiyesi bi oun ṣe n fi ohun kọrin, to si n dun ni eti bii feere.
Lati igba naa si lo ti n lo ẹbun ọhun fun orin kikọ ni awọn ile ijọsin.
Botilẹ jẹ pe o fẹran lati ma a lo ẹbun naa, to n si lọ kaakiri, Emmanuel Adepoju sọ pe awọn eniyan kii ṣaba sanwo fun oun ti wọn ba pe e si iṣẹ.





