Àlàyé rèé lórí bí Moremi Ajasoro ṣe di òrìṣà tí Ile Ife ń bọ

Àkọlé fídíò, Moremi Ajasoro: Láì má sí Moremi Ajasoro, kò lè sí ìlú tó ń jẹ́ Ile Ife
Àlàyé rèé lórí bí Moremi Ajasoro ṣe di òrìṣà tí Ile Ife ń bọ

Moremi Ajasoro jẹ obinrin takuntakun nilẹ Yoruba, ti okiki rẹ si kari ile, kari oko.

Ọpọ eeyan ni mọ diẹ nipa itan aye obinrin naa, amọ ti mọ o mọ ẹkunrẹrẹ iru eeyan to jẹ ati ipa takuntakun to ti ko si agbega ile Ife, tii se orirun ilẹ Yoruba.

Idi ree ti BBC Yoruba se morile ilu Ile Ife lati se ẹkunrẹrẹ iwadii nipa iru eeyan ti Moremi Ajasoro jẹ, ki lo de ti wọn se sọ di orisa akunlẹbọ.

Bakan naa la fẹ mọ bi obinrin naa se tan mọ ilu Ofa, ki ni orukọ awn obi rẹ ati oore nla to se silu Ile Ife ati ilẹ Yoruba lapapọ, eyi ti ko se e gbagbe.

Ọba Sunday Oluwagbemilake

“Ọdẹ ni Baba Moremi se lọ silu Offa, to fi fẹ iya rẹ”

Nigba to n salaye fun BBC Yoruba nipa itan aye Moremi Ajasoro, Ọwọ Ayekere tilu Ile Ife, Ọba Sunday Oluwagbemileke sọ pe ọmọ bibi ilu Ifẹ ni Moremi Ajasoro.

O ni Ile Yékéré nilu Ile Ife ni agbegbe Ita Akọgun ni Òkérèwè, ni agboole Moremi Ajasoro wa.

Bakan naa lo fikun pe Apa kan Ife, apa kan ilu Offa ni Moremi, orukọ baba rẹ si ni Kúrúńbà, ti iya rẹ, Olóunbẹ, si jẹ ọmọ bibi ilu Offa.

“Ọdẹ ni baba Moremi se lọ silu Offa, to si pa ọpọ ẹran ninu igbo nibẹ.,

Awọn ara Offa mu pe ki lo de to wa pa ẹran ninu igbo awọn amọ nigba ti wọn ri pe alagbara ẹda ni, wọn se ni aanu.

Nigba to n pada sile Ife, wọn fun ni ọmọbinrin kan, Olounbẹ, pe ko fi se aya, to si pada bi Moremi Ajasoro.

Ọmọrèmí ni apetan orukọ Moremi, Ile Ife ko si le gbagbe rẹ fun isẹ takun takun to se.”

Ere Moremi Ajasoro

“Bi ko ba si Moremi Ajasoro, Ko le si ohun to n jẹ ilu Ile Ife”

Ọba Sunday Oluwagbemileke wa salaye awọn igbesẹ akin ti Moremi gbe lati gba ilu Ile Ife silẹ lọwọ ẹya Ugbo to n wa ko wọn lẹru.

“Odidi ọdun kan, ti a n pe ni ọdun Edì la fi sọri Moremi, ta si maa n bọ lasiko ọdun naa, eyi to maa n waye lẹyin ọjọ mọkanlelogun ta ba pari ọdun Ọlọjọ.

Wọn ko gbọdọ lu ilu lasiko ọdun Edì naa, ti wọn yoo si gbe ina lọwọ.

Inásàn-án ni orukọ ina ti Moremi gbe dani ninu ere nla ti wọn se fun, ina yii si duro fun ina tawọn Ile Ife fi sun koriko tawọn ẹya Ugbo maa n da bora bii iwin.

Olori Aderonke Ademiluyi Ogunwusi

“Ere Moremi to wa nilu Ile Ife to tobi julọ lorilẹ ede Naijiria”

Olori Aderonke Ademiluyi Ogunwusi, tii se ọmọọba ati aya ọba Ooni Ile Ife naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa pataki Moremi nile Ife.

Olori Aderonke, tii se asoju Olori Moremi Ajasoro salaye pe ọna lati mọ riri Moremi Ajasoro ni Ọba Ooni Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Kẹta se ya ere fun iranti akọni obinrin naa.

“Ere yii ni Kabiyesi gbe kalẹ ni iranti Moremi lọdun 2016, ere naa si lo tobi julọ ni orilẹede Naijiria.

Bakan naa, ere yii lo tobi sikẹta ni iwọ oorun Afirika ta wa yii.

Ilu Ile Ife ko le gbagbe Moremi Ajasoro nitori bo se gba ilu naa lọwọ Ogun Ugbo.

Yatọ si eyi, o tun fi ọmọ rẹ kansoso rubọ lati fun Ile Ife ni ominira

Lai si Moremi Ajasoro, ko ba ti si ilu kan ti wọn yoo maa pe ni Ile Ife.”