Ọlọ́pàá mú obìnrin tó jí ara rẹ̀ gbé tó ń bèèrè mílíọ̀nù mẹ́rin náírà

Oga Olopaa pata ni Naijiria, Egbetokun

Oríṣun àwòrán, google

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti mu obinrin kan to ji ara rẹ gbe pamọ to si n beere miliọnu mẹrin owo itusilẹ lọwọ awọn ẹbi rẹ ki aṣiri to tu.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Waheed Ayilara, ṣalaye pe ọjọ Aje ni obinrin kan, Enobong Sampson, wa fẹjọ sun pe wọn ji ẹgbọn oun obinrin gbe labule Nung Oku, nijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan, l’Anambra.

O ni miliọnu mẹrin naira ni awọn ajinigbe naa fẹ gba ki wọn to le yọnda rẹ.

Ayilara ṣalaye pe awọn ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe bẹrẹ iṣẹ lori rẹ lẹsẹkẹsẹ, nigba to si di ọjọ Iṣẹgun, ọwọ ba obinrin ti wọn ji gbe naa pẹlu ọrẹkunrin rẹ.

‘’Ibuba kan lati ri wọn mu, ni Mbierebe Obio, nijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan, ipinlẹ Akwa Ibom.

“ Obinrin naa jẹwọ wa pe oun pẹlu ọrẹkunrin oun ati awọn eeyan mẹta kan lawọn jọ mọ nipa ijinigbe awuruju naa.

O ni ẹnikẹni ko ji oun gbe, oun pete ijinigbe lati fi gbowo lọwọ ẹgbọn oun to wa loke okun ni.’’

Ṣaa, gbogbo wọn ti wa lahaamọ ọlọpaa, wọn yoo si foju bale-ẹjọ.