Mo máa ń rò tẹ́lẹ̀ pé èmi nìkan ni kò ríran láyé ni, akọrin tó ní ìpèníjà ojú sọ ìrírí rẹ̀

Olorin ẹmi to ni ipenija oju, Ajihinrere Israel Adelekan Ayanfe sọ pe ‘’mo maa n ro tẹlẹ pe bo ya emi nikan ni ko riran laye ni.
Iyẹn lo jẹ ki n maa ronu gan an, mi o mọ bi mo sẹ ri gan an.
Amọ, nigba ti mo ri awọn miran naa ti wọn o riran bi temi naa, ni mo mọ pe a pọ gan an.’’
Ọmọ ọdun marundinlogoji ni Israel i ṣe, o ni ipenija oju nigba to pe ọmọ ọdun mẹfa.
‘’Gẹgẹ bi itan tawọn obi mi sọ fun mi, aisan kekere kan lo ṣe mi.
Wọn ni aisan naa le debi pe oju mi mejeeji yọ bọ sita.
Nibi ti wọn ti n gbiyanju lati fi awọn oju naa pada sinu ni mi o ti le riran mọ.
Mi o ri ẹnikan to maa duro ti mi ayafi Ọlọrun nigba ti mo ni ipenija oju.
Baba mi ku ni ọdun 2010, iya to bi mi ko si gbe pẹlu wa ki baba mi to ku.
Ko si ajọṣepọ to dan mọran laarin emi ati iya mi tori ẹlẹsin musulumi ni iya mi, nigba ti emi jẹ kristẹni.’’
Ayanfe ni ‘’awọn ti Ọlọrun fun ni ore-ọfẹ lo maa n ran mi lọwọ nipa jijẹ mimu mi.
Mo tun maa n ri owo nibi ti mo ba ti lọ kọrin lawọn ile ijọsin.
Mo tun maa n ri owo nibi kikọ awọn eeyan ni ẹkọ orin
O maa n wu mi ki n le maa ṣe bawọn iyoku ṣe maa n ṣe.’’
‘’Mi o ro pe mo le jẹ ohun ti mo jẹ lonii pẹlu iriri mi, o ṣeeṣe tori pe mo ni ipinu pe mi o ni tọrọ owo jẹun.
Mo gbagbọ pe mo si le fi oju yii riran pada,’’ Ayanfe lo sọ bẹẹ.
Ayanfe ni o ti to ọdun mẹtala ti oun ti n kọrin bayii.
‘’Yatọ si iṣẹ orin ti mo n ṣe, mo tun jẹ iranṣẹ Ọlọrun.
Mo tun ni ore-ọfẹ lati le lo ohun elo orin bii ilu, feere, mo dẹ tun maa n tẹ duuru.
Mo ba ipenija pade nile ẹkọ orin ti mo lọ tori awọn ti mo ba nibẹ ko ni ipenija oju.
Amọ, pẹlu ore-ọfẹ Ọlọrun, mo tayọ ju awọn ti ko ni ipenija oju gan an lọ,’’ Ayanfe ṣalaye.






