Oṣù Kẹ́ta oṣù mánigbàgbé tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé pọ̀jù ní Nàìjíríà

Aworan ọmọdekunrin to n ṣe ifẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ọmọ Naijiria lawọn ajinigbe ti jigbe ni ọsẹ meji to kọja.
    • Author, Azeezat Olaoluwa
    • Role, BBC News, Lagos

Ileeṣẹ ọmogun orilẹede Naijiria kede pe awọn gba awọn eeyan mẹrindinlogun kan lọwọ awọn ajinigbe to fẹ ji wọn gbe lọ lagbegbe Kajuru nipinlẹ Kaduna lọjọ Aiku to kọja.

Amọ, lalẹ ọjọ kan naa lawọn ajinigbe tun ṣọṣẹ ni agbegbe mii ni Kajuru nibi ti wọn ti gbe ọpọ eeyan lọ.

O kere tan, igba mẹfa ọtọtọ lawọn ajinigbe ti ji awọn eeyan lọ lẹkun ariwa ọrilẹede Naijiria.

Eyi to ṣẹlẹ kẹyin ni a gbọ pe awọn janduku agbebọn naa n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ al-Qaeda Ansaru.

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti n ṣiṣẹ takuntakun lati bi ọsẹ meji lori ati doola awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ.

Amọ, wọn ko tii ẹnikan kan doola ninu gbogbo awọn ti wọn ji gbe lọ.

Bi iṣẹlẹ ijinigbe ti n pọ si fihan bi awọn janduku agbebọn ṣe n lagbara sii ju awọn ẹṣọ eleto abo to n tiraka.

Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu bi awọn iṣẹlẹ yii ti n waye ti ijọba ko si le dẹkun rẹ.

''Ijọba ko gbiyanju to lati maa pese aabo fun dukia ati araalu ni Naijiria.

Awọn eleto aabo ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ti ijọba ba mọ ohun ti wọn n ṣe ni, a o ba ti ri iyatọ,'' Isa Sanusi, asoju ajọ Amnesty International ni Naijiria lo sọ bẹẹ fun BBC.

Iṣẹlẹ ijinigbe akọkọ ni Naijiria lọdun 2024 yii sẹlẹ lọjọ kẹfa oṣu Kẹta ni ipinlẹ Borno.

O kere tan, igba eeyan ni wọn jigbe lọ eyi tawọn obinrin atawọn ọmọde pọ ninu wọn.

Awọn eeyan naa n wa igi idana ninu igbo ni ipagọ ogunlede ti wọn wa ni kawọn ajinigbe to gbe wọn lọ.

Bo tilẹ jẹ pe, awọn ọmogun gbiyanju lati wa wọn, wọn ko tii ri wọn di akoko yii.

Aworan ile ẹkọ Kuriga ni Kaduna nibi tawọn ajinigbe ti ṣọṣẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Akẹkọọ ati awọn olukọ bi ọdunrun un lawọn agbebọn jigbe lọ nile ẹkọ kan ni Kaduna.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa lọjọ keje oṣu Kẹta, awọn akẹkọọ ati olukọ bi ọdunrun un lawọn janduku agbebọn ji gbe lọ nile ẹkọ kan nipinlẹ Kaduna.

Ijọba ipinlẹ Kaduna pada kede pe mejidinlogun ninu awọn akẹkọọ ọhun lo ti moribọ lọwọ awọn ajinigbe.

Aṣoju ajọ UNICEF ni Naijiria, Cristian Munduatehe, bu ẹnu atẹ lu bi iṣẹlẹ ijinigbe ti n di lemọ lẹmọ ni Naijiria.

O ni ọrọ naa nilo ki ijọba gbe igbesẹ gidi ni kiakia.

Awọn agbebọn tun ji akẹkọọ mẹẹdogun mii ni ile ẹkọ miran ni ariwa guusu ipinlẹ Sokoto lọjọ kẹsan an oṣu Kẹta.

Lẹyin ọjọ meji si asiko naa lawọn janduku agbebọn tun ji eeyan mọkanlelọgọta ni ijọba ibilẹ Kajuru ni ipinlẹ Kaduna.

Iṣẹlẹ ijinigbe to kẹyin tun waye ni kajuru nibi ti awọn janduku agbebọn ti ji eeyan to le ni ọgọrun un lọ.

Ọpọ lo ti n kọminu lori aṣẹ ti Aarẹ Bola Tinubu pa fawọn ẹṣọ eleto abo lati pese eto aabo to peye ni Naijiria.

Bi BBC ti gbiyanju lati ba ijọba sọrọ lori ọrọ eto abo to, ijọba ko tii sọ ọna ti wọn fẹ gbe gba lati dẹkun ijinigbe to n ṣẹlẹ lera lera.

Ko han si ẹnikẹni idi ti iṣẹlẹ ijinigbe fi n pọ si, amọ, iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe awọn obinrin ti wọn jigbe ṣaaju lawọn janduku agbebọn maa n lo lati maa dana fun wọn.

Awọn janduku ajinigbe ti beere owo fun itusilẹ awọn akẹkọọ ti wọn jigbe ni ibẹrẹ oṣu yii, amọ, ijọba sọ pe oun ko ni san kọbọ.

Sisan owo itusilẹ fawọn ajinigbe wọpọ ni Naijria, amọ, sisan owo itusilẹ lodi sofin.