Àwọn òntàjà ẹ̀yà Igbo fárígá nílùú Ilorin, wọ́n láwọn ò ní tajà f'ẹ́nikẹ́ni, àyàfi...

Awọn ontaja ẹya Igbo ni ilu Ilorin ni ipinlẹ Kwara tutọ soke foju gba a, wọn ni ko si ọmọ ẹgbẹ awọn to gbọdọ taja fun ẹnikẹni titi ti ijọba Kwara yoo fi ṣe ohun ti awọn n fẹ.
Gbogbo ile itaja wọn jake jado ilu Ilorin lo wa ni titi pa, ko si si tita-rira kankan lati ọdọ wọn.
BBC Yoruba rii pe gbogbo wọn lo kora jọ soju kan labẹ asia ẹgbẹ ontaja ẹya Igbo (Association of Igbo Traders) lati jiroro ati lati fẹnu ko lori ohun to kan ni sise.
Ki lo ṣẹlẹ ni pato?
Ọkan lara ọmọ ẹgbẹ náà to bẹbẹ ki a fi orukọ boun lasiri sọọ di mimọ pe ajọ to n pa owo wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara (Kwara State Internal Revenue Service) lo ti sọọbu eeyan meji lara awọn pa lori owo ori sisan.
O ni igbesẹ naa lo fa a ti awọn yoku fi dara pọ mọ wọn lati jija-n-gbara nitori ohun to ba de ba eti, o de ba imu.
O ni ti awọn ko ba dara pọ mọ awọn meji ọhun, awọn mọ wi pe awọn yoku o le moribọ ninu igbesẹ náà nitori ijọba yoo pada ti ile itaja tawọn naa pa.
O salaye pe koda, ko jẹ ọdun kan tabi ju bẹẹ lọ ni ijọba lo lati ṣi awọn sọọbu naa, awọn yoku naa ko ni ta ọja fun ẹnikẹni fun iye ọdun naa.
Awọn sọọbu meji ọhun ti ijọba ti pa ni, Ile Itaja Asaraloge Chupet ati Ile Itaja Ohun Mimu Ẹlẹrindodo Top Bizz.
Idi ti wọn fi ti awọn ile itaja naa pa
Ọmọ ẹgbẹ ontaja ẹya Igbo mii bakan naa sọ pe, gbọnmisi omi-o-to lo waye laarin awọn ati ajọ to n pa owo wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara lori owo ori.
O ni owo ori ti ijọba Kwara ni ki awọn maa san jẹ eyi to pọju ti o si le run Ileesẹ awọn.
O sọ pe lati ibẹrẹ, awọn maa n san owo gẹgẹ bi ẹgbẹ, awọn si n sanwo dede.
Ọkunrin naa ni ṣadede ni ajọ naa gbe igbesẹ tuntun wi pe ki awọn maa san owo ni ọkọọkan.
O ni ohun to jọ ni loju ni pe milionu lọna aimoye ni wọn bu fun ẹnikọọkan awọn lọdun.
Ontaja firji, ẹrọ amunawa, ẹrọ ifọsọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ọhun fi kun-un pe, millionu mọkanla naira ni wọn bu fun oun nìkan fun ọdun 2024 nikan.
O ni awọn mii, milionu mewa, mẹsan, mẹdogun ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn bu fun wọn.
O ni ohun to fa wahala leyi nitori awọn ko lee san.
Saaju ni ọjọ kọkanla osu kẹta ọdun 2024 ni alaga agba ajọ to n pa owo fun ijọba Kwara, Shade Omoniyi, ti fi lede pe, ajọ naa yoo maa ṣe isẹ wọn lai mu wahala dani.
O seleri pe ajọ naa yoo ma pawo fun idagbasoke ijọba Kwara ni ilana ati ibamu pẹlu ajọ agbaye
Kílódé tí ìjọba Kwara gbé ṣọ́ọ̀bù àwọn òntàjà Igbo tìpa ní Ilorin?

Gbọnmisi omi-o-to ṣẹlẹ lonii ọjọ Iṣẹgun niluu Ilorin laarin awọn ontaja ẹya Igbo ati ajọ to n pa owo wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara.
Aawọ to bẹ silẹ yii lo jẹ ki ajọ naa gbe ṣọọbu awọn Igbo tipa.
Niṣe lawọn ontaja ẹya Igbo naa pejọ soju kan nibi ti wọn ti koju awọn oṣiṣẹ ajọ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara ọhun.
Awọn ontaja Igbo naa kọ lati ba BBC Yoruba sọrọ, nigba ti a kan si wọn lati mọ ohun tó ṣẹlẹ gangan titi di asiko yii.
Bakan naa ni a ṣi n gbiyanju lati ba ẹka ]ijọba Kwara sọrọ lori iṣẹlẹ naa.


















