Wo àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa ẹ̀ṣọ́ ààbò Tinubu tí wọ́n kéde láti fi jẹ Ọba tuntun

Ọba Yusuf ti wọn ṣẹṣẹ yan atawọn eniyan rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Wọ́n ti kéde ọ̀gágun Nurudeen Yusuf tó jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni wọ́n ti kéde gẹ́gẹ́ bí ọba tuntun fún ìlú Ilemona ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyun, ìpínlẹ̀ Kwara.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó jáde ṣe sọ, Yusuf yóò wà gẹ́gẹ́ bí adelé, tí yóò máa ṣètò ìlú náà lọ títí yóò fi kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ológun.

Àwọn aráàlú ní pé Yusuf nìkan ni ọmọ oyè tí ìlú fà kalẹ̀ láti gba ipò Elemona ti ìlú Ilemona lẹ́yìn ìpapòdà bàbá rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara kò ì tíì sọ ohunóhun nípa ìyànsípò rẹ̀, níṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú Ilemona àti agbègbè rẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyun ti ń kan sáárá si Yusuf, tí wọ́n sì ń ki kú oríire lórí ìkéde náà.

Ta ni Nurudeen Yusuf?

Yusuf tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò náà ló jẹ́ ọmọ ọba Yusuf Omokanye Oyekanmi, Elemona ti Ilemona tó gbésẹ̀.

Ó ló sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe Offa Polytechnic níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè OND nínú ìmọ̀ Computer Science lọ́dún 2000.

Lẹ́yìn tó parí ètò ẹ̀kọ́ OND rẹ̀ ló tẹ̀síwájú lọ sí Nigerian Defence Academy, Kaduna níbi tó ti kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ Electrical-Electronics Engineering.

Láàárín ọdún 2004 sí 2005 ló tún kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Royal Military Academy Sandhurst ní orílẹ̀ èdè United Kigdom.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdún 2006 ló tún tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Nigerian Army Intelligence School tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò ààbò síwájú si nípa ètò ààbò ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà.

Yusuf tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa lílo àwọn nǹkan ìjà ogun àti ṣíṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ààbò nígbà tó lọ kópa níbi ètò Young Officer’s Course Infantry ní Kaduna lọ́dún 2007.

Ọdún 2008 ló tún parí ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí bó ṣe le ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun.

Láàárín ọdún 2009 sí 2018 ló tún lọ fún àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́kan-ò-jòkan ní orílẹ̀ èdè Mali, Pakistan, China, Israel àti United Kingdom.

Lẹ́yìn tó parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ní Jaji, ìpínlẹ̀ Kaduna ni wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ ààbò sí ààrẹ Tinubu.

Ṣáájú kí wọ́n tó yàn-án bíi ẹ̀ṣọ́ ààbò ààrẹ ni Yusuf ti wà ní ilé ààrẹ Abuja láti ọdún 2015 gẹ́gẹ́ bí Commanding Officer.

Yusuf ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ikọ̀ ọmọ ogun 119 Eko kí wọ́n tó gbe lọ sí ìlú Benin kó tó di pé wọ́n padà gbe lọ sílùú Abuja.

Ní ọdún 2005 ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun pẹ̀lú Royal Military Academy Sandhurst, UK tó sì ń tẹ̀síwájú lẹ́nu iṣẹ́ títí tó fi dépò igbákejì adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà láàárín ọdún 2017 sí 2019.

Yusuf tún ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà tó wà ní Paris, orílẹ̀ èdè France láàárín ọdún 2020 sí 2022 kó tọ di pé ó padà sí Nàìjíríà.

Ọba tuntun náà le sọ èdè Yorùbá, Haúsá, Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé dáradára.