Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ agbègbè LCDA lẹ́yìn ìdájọ́ lórí òmìnira ìjọba ìbílẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Supreme Court
Ọpọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ti wọn sẹda awọn ipinlẹ agbegbe lati ku ọwọ ijọba ibilẹ lati mo ju to eto ijọba ni ẹsẹkuku.
Ipinlẹ Eko nipinlẹ akọkọ to kọkọ sẹda awọn ijọba ibilẹ agbegbe lorilẹede Naijiria lasiko ti Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu jẹ Gomina.
Sugbọn ki ni yoo sẹlẹ si awọn ijọba agbegbe yii lẹyin idajọ ileẹjọ lori ominira ijọba ibilẹ.
BBC News ba awọn onimọ sọrọ lori ohun ti yoo sẹlẹ ati atunbọtan idajọ ile ẹjọ
Ijọba ibilẹ 772 nikan ni iwe ofin orilẹede Naijiria faye gba, ti ijọba agbegbe ko si ninu iwe ofin rara.
Ọjọgbọn Gbade Ojo, olori oṣiṣẹ ijọba fun Gomina ana ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi ba BBC Yoruba pe o ṣeeṣe ki opin de ba awọn ijọba agbegbe.
Ninu alaye rẹ, Ọjọgbọn Ojo ṣalaye pe alaga ijọba ibilẹ nikan lo ni aṣẹ lati sọ boya oun fẹ ki ijọba agbegbe wa labẹ rẹ.
“Ile ẹjọ ti fun ijọba ibilẹ ni ominira sugbọn ọjọọla ijọba agbegbe ni ko ti han si ọpọlọpọ eeyan.
“Iwe ofin orilẹede Naijiria da ijọba ibilẹ 772 mọ, ti ko si mọ ohunkohun njpa ijọba agbegbe, eyi tumọ si ijọba agbegbe ko si inu ofin orilẹede Naijiria.
“Iṣẹde ijọba agbegbe jẹ nnkan to waye labẹ lẹ ni awọn ipinlẹ to sẹda ijọba agbegbe, Bi wọn se n se tẹlẹ ni wọn ma n pin owo to wa fun ijọba ibilẹ fun awọn ijọba agbegbe naa.
“Alaga ijọba ibilẹ gbọdọ nifẹ sinu ijọba agbegbe pe ki wọn sisẹ papọ sugbọn to ba ni oun ko fẹ wọn, o ṣeeṣe ki ijọba agbegbe di ohun igbagbe.”
Alaga tẹlẹ ni ijọba ibilẹ Oluyọle nipinlẹ Oyo, Abass Aleshinloye ni idagbasoko nla ni idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ lori ominiran ijọba ibilẹ, to si gbagbọ pe ọpọ nnkan ti n waye ni ilana to yẹ ko waye lorilẹede Naijiria.
Ninu alaye rẹ, Aleshinloye ni oun ko ni gbagbọ pe iṣoro le wa fun ijọba agbegbe pẹlu bi ile ẹjọ se gbe idajọ kalẹ pẹlu bi ipinlẹ Eko se ti n se ti eto ti wọn.
“Ipinlẹ Eko ti n lo ijọba agbegbe fun igba diẹ bayii, ti wọn si n se daradara
“Mo ro pe wọn n pin owo ijọba ibilẹ pẹlu ijọba agbegbe ni ida ọgọta si ogoji.
“Ti wọn ba ti pinnu lori bi wọn se ma pin owo laarin awọn, n ko ro pe iṣoro kan le wa fun ijọba agbegbe.”
Ki ni atunbọtan ominira ijọba ibilẹ?
Ọjọgbọn Gbade Ojo tẹnu bọ ọrọ ile kun pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ko bi ara si awọn atunbọtan ti idajọ lori ominira ijọba ibilẹ le fa.
Ọjọgbọn Ojo ni ọpọ nnkan lo le waye pẹlu ominira ijọba ibilẹ paapa fun awọn olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ nitori nigba ti ijọba ibilẹ ni ominira tẹlẹ, ọpọ awọn olukọ ni wọn ko gba owo oṣu fun ọdun kan.
“Ki wọn to da SUSBEB silẹ, ọpọ awọn olukọ ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ko gba owo oṣu lati ọwọ ijọba ibilẹ fun ọdun kan.
“Ijọba ibilẹ ko tun le gba awọn oṣiṣẹ ipele keje si ẹnu iṣẹ, to si jẹ ẹka to n gba iṣẹ fun ijọba lo n ba wọn gba eeyan siṣẹ.
“Ọpọ atunbọtan lo wa ni awọn ijọba ipinlẹ ni lati wa ojutu si”
‘Gomina ti inu rẹ ko ba dun si idajọ ile ẹjọ ni erongba buburu’
Ọjọgbọn Gbade Ojo tun sọrọ lori iha ti awọn gomina kan kọ si idajọ ile ẹjọ lori omiran ijọba ibilẹ.
Ojo ni ileri ti awọn Gomina se ni lati da bobo ofin orilẹede Naijiria, ti ofin si ṣalaye yeke pe ipele mẹta ni ijọba jẹ lorilẹede Naijiria.
“Ko si nnkan ti awọn Gomina fẹ se ju ki wọn tẹlẹ aṣẹ ile ẹjọ, otitọ ọrọ niyẹn nitori nigba ti wọn bura fun wọn wọle sipo, wọn se ileri pe awọn yoo da bobo fun iwe ofin, ofin si ni ipele mẹta ni ijọba ti a ni.
“Gomina to n ba n se owo ilu mọkumọku ni inu ko dun si idajọ ile ẹjọ nitori wọn na owo ijọba ibilẹ ni ọna ti ko ba ofin mu.
“Lẹyin yẹn, awọn Gomina n lo owo ijọba ibilẹ lati se iṣẹ ilu, ti wọn si n gba oriyin fun ohun to jẹ ki ijọba ibilẹ.
“Wọn yọ owo ijọba ibilẹ lati fi se ọna, Gomina ni yoo se ọna naa, ti gbogbo eeyan yoo si ma kansara si Gomina bi pe awọn alaga kansu ko se nkankan.”
Abass Aleshiloye ni ko ya oun lẹnu ti inu awọn Gomina kan ko ba dun si idajọ ile ẹjọ nitori awọn ni wọn jẹ anfani.
“Ile ẹjọ ti sọrọ, ọrọ ile ẹjọ Supreme ni abẹ gẹ, ko si nnkan ti ẹnikẹni le ṣe lori idajọ ile ẹjọ.”















