Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau gbé ilé ẹ̀kọ́ tó wó pa akẹ́kọ̀ọ́ 22 nílùú Jos tìpa

Ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina Caleb Mutfwang ipinlẹ Plateau ti gbe ile ẹkọ Saint Academy to wo pa akẹkọọ mejilelelogun ti pa.

Gomina Mutwang tun paṣẹ pe ki iwadii kikun waye lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ninu eyi ti eeyan mejilelaadoje ti farapa.

Gomina paṣẹ yii nigba to ṣabẹwo si ile ẹkọ naa to wa ni Busa Buji ni ijọba ibilẹ ariwa ilu Jos.

Gomina sọ ninu ọrọ rẹ pe ‘’o ṣeni laanu wi pe iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, amọ, ohun ti o tumọ si naa ni pe ile ẹkọ yii ti di titi pa lẹsẹkẹsẹ niyẹn.

A ni lati ṣe eleyii kawọn oludasilẹ ile ẹkọ aladani mii naa le kẹkọọ lara ohun to ṣẹlẹ.

Gomina sọ pe erongba awọn eeyan lati wa owo ko gbọdọ ẹmi ẹnikẹni lọ.

‘’Ni bayii, a ni lati ṣe ayẹwo gbogbo ile ẹkọ lati le mọ bo ya awọn yara igbẹkọọ wọn duro deedee.

A gbọdọ ri iadniloju pe awọn eeyan le maa gbe ninu awọn ile ẹkọ yii lai sewu.

Lana ọjọ Ẹti ni ile ẹkọ naa ṣadeedee wo nigba tawọn akẹkọọ m gbẹkọ lọwọ.

Iroyin fidi rẹ mulẹ wọn ti ko oku awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ si oniruuru mọṣuari, nigba tawọn to ṣeeṣe nibi iṣẹlẹ naa n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Plateau ti kede ọjọ mẹta fun idaro awọn to ku ninu iṣẹlẹ ile ẹkọ to dawo naa.

Èèyàn 22 ló kú, tí àwọn 132 míì ṣèṣe nílé ẹ̀kọ́ tó dàwó ní Jos

Awọn oṣìṣẹ́ aláàbò níbi ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó

Oríṣun àwòrán, NEMA/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba ipinlẹ Plateau ti sọ pe apapọ eeyan mejilelogun lo ti jade laye nibi ile ẹkọ to dawo, ti ọgunrun ati mejilelọgbọn mii si farapa.

Agbegbe Busa Buji, ni ijọba ibilẹ Ariwa Jos, ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Ẹti.

Kọmiṣọna eto iroyin, Musa Ashoms lo fi ọrọ lede ninu atẹjade kan lalẹ ọjọ Ẹti.

Ashoms sọ pe “ni nnkan biii aaago mẹfa irọlẹ, eeyan 154 ni a ti yọ jade labẹ ile to dawo, amọ o ṣeni laanu pe eeyan mejilelogun ni a fidi rẹ mulẹ pe o jade laye.

“Awọn akẹkọọ ati olukọ to farapa ti n gba itọju kaakiri awọn ilewosan niluu Jos.”

Ṣaaju ni Ashoms ti kọkọ ṣabẹwo sile ẹkọ alaja meji naa to si sọ pe bo tilẹ jẹ pe irinwo akẹkọọ lo wa nibẹ, igba akẹkọọ lo wa lapa ibi to dawo.

O fi kun pe awọn oṣiṣẹ pajawiri ti ko awọn to moribọ lọ sile iwosan fun itọju.

O ni “lati ri daju pe awọn ti ọrọ naa kan gba itọju to peye, ijọba ti ke si gbogbo ile iwosan ni Jos lati mu itọju awọn eeyan naa ni ọkunkundun lai kọkọ ro ti owo atawọn nnkan mii.”

“Gomina amofin Mutfwang ti sọ fun awọn ile iwosan ki wọn tẹwọgba gbogbo awọn to ṣeṣe.”

Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kú, àwọn mìíràn farapá bí ilé ẹ̀kọ́ ṣe dàwó lásìkò ìdánwò

Ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kò dín ní akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínlógún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó ní ìpínlẹ̀ Plateau.

Àjọ tọ ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà lójú òpó X rẹ̀ ní akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ni ogójì ni àwọn ti rí yọ lábẹ́ ilé náà tí àwọn sì ti gbé wọn lọ sílé ìwòsàn.

NEMA ní lára àwọn ilé ìwòsàn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń gba ìtọ́jú ni Bingham University Teaching Hospital, Plateau Specialist Hospital, Jos University Hospital àti AG Hospital.

Àjọ náà ní ìdóòlà ẹ̀mí tí àwọn ń ṣe níbẹ̀ ti parí àti pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ti gba ìwòsàn tí wọ́n sì ti lọ sílé wọn.

Bákan náà ni wọ́n ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọgbọ̀n ló ṣì wà nílé ìwòsàn tí wan ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

“Ó ṣeni láàánú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan pàdánù ẹ̀mí wọn àmọ́ a ò tíì le sọ ní pàtó iye tí wọ́n jẹ́.”

Ile ẹkọ to dawo naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilé ẹ̀kọ́ dàwó lásìkò ìkẹ́kọ̀ọ́, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kú, ètò ìdóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó há sábẹ́ àwókù ilé bẹ̀rẹ̀

Àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì

Oríṣun àwòrán, NEMA/X

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun báyìí láti dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ tó ṣàdédé dàwọ lójijì ní ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Plateau.

Ilé ẹ̀kọ́ náà, Saint Academy tó jẹ́ ilé alájà méjì ní Busa ní ìjọba ìbílẹ̀ Jos North, ìpínlẹ̀ Plateau ló ṣàdédé dàwó lulẹ̀ lásìkò tí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ń lọ lọ́wọ́.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe wí, nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀, ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje ni ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàdédé dàwó.

Níṣe ni ìbẹ̀rùbojo gba ọkàn àwọn èèyàn pàápàá àwọn òbí pé àwọn ọmọ wọn ti padánù ẹ̀mí wọn tàbí farapa síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn òṣìṣẹ́ ààbò, tó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mọjútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ń mọjútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Nàìjíríà, NEMA lójú òpó X wọ́n ní ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn síbi ìjàmbá ilé tó dàwó náà.

'Mo kàn gbọ́ gbì níwájú ilé ẹ̀kọ́ náà ti mo wà ni'

Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tí ìjàmbá náà ṣojú rẹ̀, Samuel Akpan sọ fún BBC News Pidgin bí ìjàmbá ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe wáyé.

Samuel tí òun náà wà lára àwọn tó ń gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn sọ pé ọ̀kan lára àwọn ilé ìtajà tó wà níwájú ilé ẹ̀kọ́ náà ni òun wà nígbà tí òun gbọ́ ariwo ńlá kan.

Ó ní bí òun ṣe gbọ́ ariwo náà ni òun tara gìrì láti mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ tí òun sì ri pé ilé ẹ̀kọ́ náà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ibẹ̀ ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́ ló ti rì.

“A ò mọ nǹkan tó yẹ kí a ṣe nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kò sí ohun èlò tí a lè lò láti fi dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, a nílò láti dúró de àwọn òṣìṣẹ́ ààbò láti wá ràn wá lọ́wọ́.”

Ó ní àwọn ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tí àwọn èèyàn náà sì jáde láàyè.

Ó sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ṣì há sábẹ́ ilé náà àti pé òun ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n máa rí àwọn yòókù yọ.

Ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó

Ẹlòmíràn tí ìjàmbá ọ̀hún tún ṣojú rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ náà rì wọnú ilẹ̀ ni lòdì ìròyìn tí àwọn èèyàn ń gbé kiri pé ilé náà dàwó ni.

Ó ní nígbà tí òun rí ìròyìn náà lórí ayélujára ni òun sáré lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí òun sì ri pé ilé náà ti rì.

Ó ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ipele JSS 1 àti 2 tí wan ń lo àwọn yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ ṣì wà lábẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n há sí nítorí àwọn tọ wà lókè ni wan ṣì ń rí yọ báyìí.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló wà ní ìkàlẹ̀ láti ri pé wan dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.